Jeremias 27
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YOR) vs NVT
1 Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣèjọba Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wí pé.
1 Jeremias recebeu esta mensagem do S enhor no início do reinado de Zedequias, filho de Josias, rei de Judá.
2 Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Ṣe àjàgà àti ọ̀pá irin fún ara rẹ, kí o sì fiwé ọrùn rẹ.
2 Assim me disse o S enhor : “Faça um jugo, ponha-o sobre o pescoço e prenda-o com cordas de couro.
3 Kí o rán ọ̀rọ̀ sí ọba ti Edomu, Moabu, Ammoni, Tire àti Sidoni láti ọwọ́ àwọn ikọ̀ tí ó wá sí Jerusalẹmu sọ́dọ̀ Sedekiah ọba Juda.
3 Depois, envie mensagens aos reis de Edom, Moabe, Amom, Tiro e Sidom por meio dos embaixadores que vieram ver o rei Zedequias em Jerusalém.
4 Kí o sì pàṣẹ fún wọn láti wí fún àwọn olúwa wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: “Sọ èyí fún àwọn olúwa rẹ.
4 Diga-lhes que transmitam esta mensagem a seus senhores: ‘Assim diz o S enhor dos Exércitos, o Deus de Israel:
5 Pẹ̀lú agbára ńlá mi àti ọwọ́ nínà mi ni Èmi dá ayé, ènìyàn àti ẹranko tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, mo sì fún ẹni tí ó wu ọkàn mi.
5 Com minha grande força e meu braço poderoso, fiz a terra, todas as pessoas e todos os animais. Isso tudo é meu, e posso entregá-lo a quem eu quiser.
6 Nísinsin yìí, Èmi yóò fa gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ fún Nebukadnessari ọba Babeli ìránṣẹ́ mi; Èmi yóò sì mú àwọn ẹranko búburú wọ̀n-ọn-nì jẹ́ tirẹ̀.
6 Agora, entregarei suas nações a meu servo, Nabucodonosor, rei da Babilônia. Coloquei tudo debaixo de seu controle, até os animais selvagens.
7 Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóò máa sìn ín àti àwọn ọmọdọ́mọ rẹ̀ títí ilẹ̀ rẹ yóò fi dé; ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba ńlá ni yóò tẹríba fún.
7 Todas as nações servirão a ele, seu filho e seu neto, até terminar o tempo deles. Então, muitas nações e grandes reis conquistarão e dominarão a Babilônia.
8 “ ‘ “Ṣùgbọ́n tí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan kò bá ní sin Nebukadnessari ọba Babeli, tàbí kí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní abẹ́ àjàgà rẹ̀, Èmi yóò fi ìyà jẹ orílẹ̀-èdè náà nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, ni Olúwa wí títí Èmi yóò fi run wọ́n nípa ọwọ́ rẹ̀.
8 Submetam-se, portanto, ao rei da Babilônia e sirvam-no. Coloquem o pescoço debaixo do jugo da Babilônia. Eu castigarei qualquer nação que se recusar a servi-lo. Enviarei guerra, fome e doença sobre essa nação até que a Babilônia a conquiste.
9 Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn wòlíì yín, àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, àwọn tí ń rọ́ àlá fún un yín, àwọn oṣó yín, tàbí àwọn àjẹ́ yín tí wọ́n ń sọ fún un yín pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli.’
9 “‘Não deem ouvidos a seus falsos profetas, adivinhos, intérpretes de sonhos, médiuns e feiticeiros, que dizem: ‘O rei da Babilônia não os dominará’.
10 Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún un yín èyí tí yóò mú u yín jìnnà réré kúrò ní ilẹ̀ yín; kí Èmi kí ó lè lé yín jáde, kí ẹ̀yin ó sì ṣègbé.
10 São todos mentirosos, e suas mentiras os levarão a ser expulsos da terra. Eu os expulsarei e os enviarei para longe, e vocês morrerão.
11 Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀-èdè kankan bá tẹ orí rẹ̀ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, tí ó sì sìn ín, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè náà wà lórí ilẹ̀ rẹ̀ láti máa ro ó, àti láti máa gbé ibẹ̀ ni Olúwa wí.” ’ ”
11 Mas a nação que se sujeitar ao rei da Babilônia poderá continuar em sua terra e cultivá-la. Eu, o S enhor , falei!’”.
12 Èmi sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Sedekiah ọba Juda wí pé: “Tẹ orí rẹ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, sìn ín ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ yóò sì yè.
12 Depois, repeti a mesma mensagem a Zedequias, rei de Judá: “Submeta-se ao jugo do rei da Babilônia e de seu povo, e vocês viverão.
13 Kí ló dé tí ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, èyí tí Olúwa fi ń halẹ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí kò bá sin ọba Babeli?
13 Por que você e seu povo morreriam? Por que escolher guerra, fome e doença que o S enhor trará contra toda nação que não se submeter ao rei da Babilônia?
14 Ẹ má ṣe fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tí ó ń sọ wí pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli,’ nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín.
14 Não deem ouvidos aos falsos profetas que lhes dizem: ‘O rei da Babilônia não os dominará’. São mentirosos.
15 ‘Èmi kò rán wọn ni Olúwa wí. Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Nítorí náà, Èmi yóò lé wọn, wọn yóò sì ṣègbé, ẹ̀yin pẹ̀lú àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún un yín.’ ”
15 Assim diz o S enhor : ‘Não enviei esses profetas. Eles contam mentiras em meu nome. Por isso expulsarei vocês desta terra. Todos vocês morrerão, junto com todos esses profetas’”.
16 Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ẹ má ṣe fetí sí nǹkan tí àwọn wòlíì ń sọ pé, ‘Láìpẹ́ ohun èlò ilé Olúwa ni a ó kó padà láti Babeli,’ àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ. Ẹ má tẹ́tí sí wọn.
16 Então falei aos sacerdotes e ao povo e disse: “Assim diz o S enhor : ‘Não deem ouvidos aos profetas que afirmam que, em breve, serão devolvidos os objetos preciosos que foram tirados do meu templo e levados para a Babilônia. É tudo mentira.
17 Má ṣe tẹ́tí sí wọn, ẹ máa sin ọba Babeli, ẹ̀yin yóò sì yè. Èéṣe tí ìlú yóò fi di ahoro?
17 Não lhes deem ouvidos. Submetam-se ao rei da Babilônia, e viverão. Por que provocar a destruição desta cidade inteira?
18 Tí wọ́n bá jẹ́ wòlíì, tí wọ́n sì ní ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ kí wọ́n bẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun kí a má ṣe kó ohun èlò tí ó kù ní ilé Olúwa àti ní ààfin ọba Juda àti Jerusalẹmu lọ sí Babeli.
18 Se, de fato, eles são profetas e transmitem mensagens do S enhor , que orem ao S enhor dos Exércitos e supliquem que os objetos que restam no templo do S enhor , no palácio do rei e em Jerusalém não sejam levados para a Babilônia’.
19 Nítorí pé, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ nípa àwọn opó, omi Òkun ní ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti ní ti ohun èlò ìyókù tí ó kù ní ìlú náà.
19 “Pois assim diz o S enhor dos Exércitos acerca das colunas à entrada do templo, do tanque de bronze chamado Mar, das bases móveis e de todos os outros objetos cerimoniais.
20 Èyí tí Nebukadnessari ọba Babeli kò kó lọ nígbà tí ó mú Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn ọlọ́lá Juda àti Jerusalẹmu.
20 Nabucodonosor, rei da Babilônia, os deixou aqui quando levou Joaquim, filho de Jeoaquim, rei de Judá, para o exílio na Babilônia com todos os nobres de Judá e Jerusalém.
21 Lóòótọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí nípa àwọn ohun ìṣúra tí ó ṣẹ́kù ní ilé Olúwa àti ní ààfin ọba Juda àti ní Jerusalẹmu:
21 Assim diz o S enhor dos Exércitos, o Deus de Israel, a respeito dos objetos preciosos que restaram no templo e no palácio do rei de Judá:
22 ‘A ó mú wọn lọ sí ilẹ̀ Babeli, ní ibẹ̀ ni wọn ó sì wà títí di ìgbà tí mo bá padà,’ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa. ‘Lẹ́yìn èyí, Èmi yóò mú wọn padà, Èmi yóò sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ ní ibí yìí.’ ”
22 ‘Todos eles serão levados para a Babilônia e ali ficarão até que eu mande buscá-los’, diz o S enhor . ‘Então os trarei de volta a Jerusalém’”.
Atalhos do teclado
- Capítulo anterior←
- Próximo capítulo→
- Versículo anteriork
- Próximo versículoj
- Limpar seleçãoEsc
- Esta ajuda?
Estude este capítulo no WhatsApp
Peça à IA da Bíblia Fala para explicar Jeremias 27, comparar traduções ou montar um estudo — tudo direto pelo WhatsApp.