Ezequiel 25

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YOR) vs NVI

Sair da comparação
NVI Nova Versão Internacional
1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
1 Esta palavra do Senhor veio a mim:
2 “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí àwọn ará Ammoni kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí wọn.
2 "Filho do homem, vire o rosto contra os amonitas e profetize contra eles.
3 Sì wí fún àwọn ará Ammoni pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè tí ó wí pé. Nítorí tí ìwọ wí pé, “Á hà!” Sí ibi mímọ́ mi nígbà tí ó di àìlọ́wọ̀ àti sí orí ilẹ̀ Israẹli nígbà tí ó di ahoro; àti sí ilẹ̀ Juda, nígbà tí wọ́n lọ sí ìgbèkùn,
3 Diga-lhes: ‘Ouçam a palavra do Soberano Senhor. Assim diz o Soberano Senhor: Visto que vocês exclamaram: "Ah! Ah! " quando o meu santuário foi profanado, quando a terra de Israel foi arrasada e quando a nação de Judá foi para o exílio,
4 kíyèsi i, nítorí náà ni èmi yóò fi fi ọ lé àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn lọ́wọ́ ni ohun ìní. Wọn yóò sì gbé ààfin wọn kalẹ̀ nínú rẹ, wọn yóò sì gbé ibùgbé wọn nínú rẹ, wọn yóò jẹ èso rẹ, wọn yóò sì mu wàrà rẹ.
4 vou entregar vocês como propriedade do povo do oriente. Eles instalarão seus acampamentos e armarão suas tendas no meio de vocês; comerão suas frutas e beberão seu leite.
5 Èmi yóò sì sọ Rabba di ibùjẹ, fún àwọn ìbákasẹ àti àwọn ọmọ Ammoni di ibùsùn fún agbo ẹran. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.
5 Farei de Rabá num cercado para camelos e Amom um local de descanso para ovelhas. Então vocês saberão que eu sou o Senhor.
6 Nítorí báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí. Nítorí pé ìwọ pàtẹ́wọ́, ìwọ sì jan ẹsẹ̀ mọ́lẹ̀, tí ìwọ ń yọ̀ pẹ̀lú gbogbo àrankàn rẹ sí ilẹ̀ Israẹli
6 Porque assim diz o Soberano Senhor: Visto que vocês bateram palmas e pularam de alegria com o coração cheio de maldade contra Israel,
7 nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mi lé ọ, èmi yóò sì fi ọ fún àwọn aláìkọlà fún ìkógun. Èmi yóò sì gé ọ kúrò láàrín àwọn ènìyàn, èmi yóò sì jẹ́ kí o parun kúrò ni ilẹ̀ gbogbo. Èmi yóò sì pa ọ́ run, ìwọ yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ”
7 por essa razão estenderei o meu braço contra vocês e os darei às nações como despojo. Eliminarei vocês do meio das nações e os exterminarei do meio dos povos. Eu os destruirei, e vocês saberão que eu sou o Senhor’.
8 “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí pé Moabu àti Seiri sọ wí pé, “Wò ó, ilé Juda ti dàbí gbogbo àwọn kèfèrí,”
8 "Assim diz o Soberano Senhor: ‘Uma vez que Moabe e Seir disseram: "Vejam, a nação de Judá se tornou como todas as outras nações",
9 nítorí náà, Èmi yóò ṣí Moabu sílẹ̀ láti àwọn ìlú gbogbo tí ó wà ní ààlà rẹ̀, ògo ilẹ̀ náà, Beti-Jeṣimoti, Baali-Meoni àti Kiriataimu.
9 por essa razão abrirei o flanco de Moabe, começando por suas cidades fronteiriças, Bete-Jesimote, Baal-Meom e Quiriataim, que são a glória dessa terra.
10 Èmi yóò fi Moabu pẹ̀lú àwọn ará Ammoni lé àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn ní ìní, kí a má bà á lè rántí àwọn ará Ammoni láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.
10 Darei Moabe junto com os amonitas como propriedade ao povo do oriente. Os amonitas não serão lembrados entre as nações,
11 Èmi yóò sì mú ìdájọ́ sẹ sí Moabu lára, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ”
11 e a Moabe trarei castigo. Então eles saberão que eu sou o Senhor’.
12 “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí pé: ‘Nítorí pé Edomu gbẹ̀san lára ilé Juda, ó sì jẹ̀bi gidigidi nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀,
12 "Assim diz o Soberano Senhor: ‘Visto que Edom vingou-se da nação de Judá e com isso trouxe grande culpa sobre si,
13 nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí pé: Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Edomu èmi yóò sì pa àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko rẹ̀. Èmi yóò fi ṣófo láti Temani dé Dedani yóò ti ipa idà ṣubú.
13 assim diz o Soberano Senhor: Estenderei o braço contra Edom e matarei os seus homens e os seus animais. Eu o arrasarei, e desde Temã até Dedã eles cairão pela espada.
14 Èmi yóò gbẹ̀san lára Edomu láti ọwọ́ àwọn ènìyàn mi Israẹli, wọn sì ṣe sí Edomu gẹ́gẹ́ bí ìbínú àti ìrunú mi, wọn yóò mọ̀ ìgbẹ̀san mi ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ”
14 Eu me vingarei de Edom pelas mãos do meu povo Israel, e este lidará com Edom de acordo com a minha ira e a minha indignação; eles conhecerão a minha vingança, palavra do Soberano Senhor’.
15 “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí pé: ‘Nítorí tí àwọn ará Filistini hùwà ẹ̀san tí wọ́n sì gbẹ̀san pẹ̀lú odì ní ọkàn wọn, àti pẹ̀lú ìkórìíra gbangba àtijọ́ ní wíwá ọ̀nà láti pa Juda run,
15 "Assim diz o Soberano Senhor: ‘Uma vez que a Filístia agiu por vingança e com maldade no coração, e com antiga hostilidade buscou destruir Judá,
16 nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí pé, “Èmi ti ṣetán láti na ọwọ́ mi jáde sí àwọn ará Filistini, èmi yóò sì ké àwọn ará Kereti kúrò, èmi yóò sì pa àwọn tí ó kù ní etí kún run.
16 assim diz o Soberano Senhor: estou a ponto de estender meu braço contra os filisteus. Eliminarei os queretitas e destruirei os que restarem no litoral.
17 Èmi yóò sì gbẹ̀san ńlá lára wọn nípa ìbáwí gbígbóná; wọn yóò sì mọ̀ wí pé, Èmi ni Olúwa. Nígbà tí èmi yóò gba ẹ̀san lára wọn.” ’ ”
17 Executarei neles grande vingança e os castigarei na minha ira. Então, quando eu me vingar deles, saberão que eu sou o Senhor’ ".

Ler em outra tradução

Comparar com outra

Estude este capítulo no WhatsApp

Peça à IA da Bíblia Fala para explicar Ezequiel 25, comparar traduções ou montar um estudo — tudo direto pelo WhatsApp.