2 Samuel 10
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YOR) vs ARIB
1 Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, ọba àwọn ará Ammoni sì kú, Hanuni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
1 Depois disto morreu o rei dos amonitas, e seu filho Hanum reinou em seu lugar.
2 Dafidi sì wí pé, “Èmi yóò ṣe oore fún Hanuni ọmọ Nahaṣi gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ sì ti ṣe oore fún mi.” Dafidi sì ránṣẹ́ láti tù Hanuni nínú láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá, nítorí ti baba rẹ̀.
2 Então disse Davi: usarei de benevolência para com Hanum, filho de Naás, como seu pai usou de benevolência para comigo. Davi, pois, enviou os seus servos para o consolar acerca de seu pai; e foram os servos de Davi à terra dos amonitas.
3 Àwọn olórí àwọn ọmọ Ammoni sì wí fún Hanuni olúwa wọn pé, “Ǹjẹ́ o rò pé Dafidi ń bu ọlá fún baba rẹ nígbà tí ó rán ènìyàn wá láti bá ọ kẹ́dùn? Kò ha ṣe pé Dafidi rán àwọn ìránṣẹ́ sí ọ láti wo ìlú àti láti yọ́ ọ wò àti láti gbà ọ́.”
3 Então disseram os príncipes dos amonitas a seu senhor, Hanum: Pensas, porventura, que foi para honrar teu pai que Davi te enviou consoladores? Não te enviou antes os seus servos para reconhecerem esta cidade e para a espiarem, a fim de transtorná-la?
4 Hanuni sì mú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi ó fá apá kan irùngbọ̀n wọn, ó sì gé ààbọ̀ kúrò ní agbádá wọn, títí ó fi dé ìdí wọn, ó sì rán wọn lọ.
4 Pelo que Hanum tomou os servos de Davi, rapou-lhes metade da barba, cortou-lhes metade dos vestidos, até as nádegas, e os despediu.
5 Wọ́n sì sọ fún Dafidi, ó sì ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí tí ojú ti àwọn ọkùnrin náà púpọ̀: ọba sì wí pé, “Ẹ dúró ní Jeriko títí irùngbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ni kí ẹ tó máa bọ̀.”
5 Quando isso foi dito a Davi, enviou ele mensageiros a encontrá-los, porque aqueles homens estavam sobremaneira envergonhados; e mandou dizer-lhes: Deixai-vos estar em Jericó, até que vos torne a crescer a barba, e então voltai.
6 Àwọn ará Ammoni sì ri pé, wọ́n di ẹni ìríra níwájú Dafidi, àwọn ọmọ Ammoni sì ránṣẹ́, wọ́n sì fi owó bẹ́ ogún àwọn ará Siria ti Beti-Rehobu; àti Siria-Soba, ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) ẹlẹ́ṣẹ̀ àti ti ọba Maaka, ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin àti ti Tobu ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ọkùnrin lọ́wẹ̀.
6 Vendo, pois, os amonitas que se haviam feito abomináveis para com Davi, enviaram e alugaram dos sírios de Bete-Reobe e dos sírios de Bete-Reobe e dos sírios de Sobá vinte mil homens de infantaria, e do rei de Maacá mil homens, e dos homens de Tobe doze mil.
7 Dafidi sì gbọ́, ó sì rán Joabu, àti gbogbo ogún àwọn ọkùnrin alágbára.
7 O que ouvindo Davi, enviou contra eles a Joabe com todo o exército dos valentes.
8 Àwọn ọmọ Ammoni sì jáde wá, wọ́n sì tẹ́ ogun ní ẹnu odi; ará Siria-Soba, àti ti Rehobu, àti Tobu, àti Maaka, wọ́n sì tẹ ogun ni pápá fún ara wọn.
8 E saíram os amonitas, e ordenaram a batalha a entrada da porta; mas os sírios de Zobá e de Reobe, e os homens de Tobe e de Maacá estavam à parte no campo.
9 Nígbà tí Joabu sì rí i pé ogun náà dojúkọ òun níwájú àti lẹ́yìn, ó sì yàn nínú gbogbo àwọn akíkanjú ọkùnrin ní Israẹli, ó sì tẹ́ ogun kọjú sí àwọn ará Siria.
9 Vendo, pois, Joabe que a batalha estava preparada contra ele pela frente e pela retaguarda, escolheu alguns homens dentre a flor do exército de Israel, e formou-os em linha contra os sírios;
10 Ó sì fi àwọn ènìyàn tí ó kù lé Abiṣai àbúrò rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè tẹ ogun kọjú sí àwọn ọmọ Ammoni.
10 e entregou o resto do povo a seu irmão Abisai, para que o formasse em linha contra os amonitas.
11 Ó sì wí pé, “Bí agbára àwọn ará Siria bá pọ̀ ju èmi lọ, ìwọ yóò sì wá ràn mí lọ́wọ́, ṣùgbọ́n bí ọwọ́ àwọn ọmọ Ammoni bá sì pọ̀jù ọ́ lọ, èmi ó sì wá ràn ọ́ lọ́wọ́.
11 E disse-lhe: Se os sírios forem mais fortes do que eu, tu me virás em socorro; e se os amonitas forem mais fortes do que tu, eu irei em teu socorro.
12 Mú ọkàn lè, jẹ́ kí a ṣe onígboyà nítorí àwọn ènìyàn wa, àti nítorí àwọn ìlú Ọlọ́run wa; Olúwa yóò sì ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ̀.”
12 Tem bom ânimo, e sejamos corajosos pelo nosso povo, e pelas cidades de nosso Deus; e faça o Senhor o que bem lhe parecer.
13 Joabu àti àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì bá àwọn ará Siria pàdé ìjà, wọ́n sì sá níwájú rẹ̀.
13 Então Joabe e o povo que estava com ele travaram a peleja contra os sírios; e estes fugiram diante dele.
14 Nígbà tí àwọn ọmọ Ammoni sì rí i pé àwọn ará Siria sá, àwọn pẹ̀lú sì sá níwájú Abiṣai, wọ́n sì wọ inú ìlú lọ. Joabu sì padà kúrò lẹ́yìn àwọn ọmọ Ammoni, ó sì wá sí Jerusalẹmu.
14 E, vendo os amonitas que os sírios fugiam, também eles fugiram de diante de Abisai, e entraram na cidade. Então Joabe voltou dos amonitas e veio para Jerusalém.
15 Nígbà tí àwọn ará Siria sì rí i pé àwọn ṣubú níwájú Israẹli, wọ́n sì kó ara wọn jọ
15 Os sírios, vendo que tinham sido derrotados diante de Israel, trataram de refazer-se.
16 Hadadeseri sì ránṣẹ́, ó sì mú àwọn Siria tí ó wà ní òkè odò Eufurate jáde wá, wọ́n sì wá sí Helami; Sobaki olórí ogun Hadadeseri sì ṣe olórí wọn.
16 E Hadadézer mandou que viessem os sírios que estavam da outra banda do rio; e eles vieram a Helã, tendo à sua frente Sobaque, chefe do exército de Hadadézer.
17 Nígbà tí a sọ fún Dafidi, ó sì kó gbogbo Israẹli jọ, wọ́n sì kọjá Jordani, wọ́n sì wá sí Helami, àwọn ará Siria sì tẹ́ ogun kọjú sí Dafidi, wọ́n sì bá a jà.
17 Davi, informado disto, ajuntou todo o Israel e, passando o Jordão, foi a Helã; e os sírios se puseram em ordem contra Davi, e pelejaram contra ele.
18 Àwọn ará Siria sì sá níwájú Israẹli, Dafidi sì pa nínú àwọn ará Siria ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àwọn oníkẹ̀kẹ́, àti ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ẹlẹ́ṣin, wọ́n sì kọlu Sobaki olórí ogun wọn, ó sì kú níbẹ̀.
18 Os sírios, porém, fugiram de diante de Israel; e Davi matou deles os homens de setecentos carros, e quarenta mil homens de cavalaria; e feriu a Sobaque, general do exército, de sorte que ele morreu ali.
19 Nígbà tí gbogbo àwọn ọba tí ó wà lábẹ́ Hadadeseri sì rí i pé wọ́n di bíbì ṣubú níwájú Israẹli, wọ́n sì bá Israẹli làjà, wọ́n sì ń sìn wọ́n.
19 Vendo, pois, todos os reis, servos de Hadadézer, que estavam derrotados diante de Israel, fizeram paz com Israel, e o serviram. E os sírios não ousaram mais socorrer aos amonitas.
Atalhos do teclado
- Capítulo anterior←
- Próximo capítulo→
- Versículo anteriork
- Próximo versículoj
- Limpar seleçãoEsc
- Esta ajuda?
Estude este capítulo no WhatsApp
Peça à IA da Bíblia Fala para explicar 2 Samuel 10, comparar traduções ou montar um estudo — tudo direto pelo WhatsApp.