1 Crônicas 12
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YOR) vs VC
1 Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní Siklagi, nígbà tí ó sá kúrò níwájú Saulu ọmọ Kiṣi (wọ́n wà lára àwọn jagunjagun ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́ láti ibi ìjà.
1 Eis os que foram juntar-se a Davi, em Siceleg, quando ainda devia conservar-se longe de Saul, filho de Cis; estão contados entre os homens valentes que lhe prestaram auxílio durante a guerra.
2 Wọ́n sì mú wọn pẹ̀lú ìtẹríba wọ́n sì lágbára láti ta ọfà tàbí láti ta kànnàkànnà òkúta ní ọwọ́ òsì tàbí ní ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n sì jẹ́ ìbátan ọkùnrin Saulu láti ẹ̀yà Benjamini):
2 Eram arqueiros, exercitados em lançar pedras, tão bem com a mão esquerda como com a direita, e a atirar flechas com o arco; eram irmãos de Saul, de Benjamim.
3 Ahieseri olórí wọn àti Joaṣi àwọn ọmọ Ṣemaah ará Gibeah:
3 Seus chefes eram Aieser, em seguida Joás, ambos filhos de Samaa, de Gabaa; Jaziel e Falet, filhos de Azmot; Baraca; Jeú, de Anatot;
4 Àti Iṣmaiah ará Gibeoni, ọkùnrin alágbára kan lára àwọn ọgbọ̀n ẹni tí ó jẹ́ olórí nínú àwọn ọgbọ̀n;
4 Samaías, de Gabaon, valente entre os trinta e chefe dos trinta; Jeremias; Jeeziel; Joanã; Jezabad, de Gedera; Eluzai; Jerimut; Baalia; Samaria;
5 Elusai, Jerimoti, Bealiah, Ṣemariah àti Ṣefatia ará Harufiti;
5 Safatia, de Haruf;
6 Elkana, Iṣiah, Asareeli, Joeseri àti Jaṣobeamu ará Kora;
6 Elcana, Jesia, Azareel, Joeser e Jesbão, filhos de Coré;
7 àti Joẹla, àti Sebadiah àwọn ọmọ Jerohamu láti Gedori.
7 Joela e Zabadia, filhos de Jeroão, de Gedor.
8 Díẹ̀ lára àwọn ará Gadi yà sọ́dọ̀ Dafidi ní ibi gíga ní aginjù. Wọ́n sì jẹ́ onígboyà ológun tí ó múra fún ogun tí ó sì lágbára láti di asà àti ẹṣin mú. Ojú wọn sì dàbí ojú kìnnìún, wọ́n sì yára bí àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè.
8 Homens valentes dos gaditas passaram para Davi nas cavernas do deserto, guerreiros exercitados no combate, que sabiam manejar o escudo e a lança; tinham o aspecto de leões e a agilidade das gazelas das montanhas.
9 Eseri sì jẹ́ ìjòyè,
9 Ezer era seu chefe; Obdias, o segundo; Eliab, o terceiro;
10 Miṣimana ẹlẹ́ẹ̀kẹrin, Jeremiah ẹlẹ́ẹ̀karùnún
10 Masmana, o quarto; Jeremias, o quinto;
11 Attai ẹlẹ́ẹ̀kẹfà, Elieli èkeje,
11 Eti, o sexto; Eliel, o sétimo;
12 Johanani ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ Elsabadi ẹlẹ́ẹ̀kẹsàn-án
12 Joanã, o oitavo; Elzebad, o nono;
13 Jeremiah ẹlẹ́ẹ̀kẹwàá àti Makbannai ẹlẹ́ẹ̀kọkànlá.
13 Jeremias, o décimo; Macbanai, o undécimo.
14 Àwọn ará Gadi wọ́n sì jẹ́ olórí ogun; ẹni tí ó kéré jù sì jẹ́ àpapọ̀ ọgọ́rùn-ún, àti fún ẹni tí ó pọ̀jù fún ẹgbẹ̀rún (1,000).
14 Eram estes os filhos de Gad, chefes do exército; o menor deles, sozinho, podia vencer cem; o mais forte, mil.
15 Àwọn ni ẹni tí ó rékọjá Jordani ní oṣù àkọ́kọ́ nígbà tí ó kún bo gbogbo bèbè rẹ̀, wọ́n sì lé gbogbo àwọn tí ó ń gbé nínú àfonífojì, lọ sí ìlà-oòrùn àti níhà ìwọ̀-oòrùn.
15 Foram eles que atravessaram o Jordão, no primeiro mês, quando o rio costuma transbordar em todo o seu curso, e que puseram em fuga todos os habitantes dos vales, a leste e a oeste.
16 Ìyókù ará Benjamini àti àwọn díẹ̀ ọkùnrin láti Juda lọ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní ibi gíga.
16 Houve também filhos de Benjamim e de Judá, que vieram aliar-se a Davi nas cavernas.
17 Dafidi sì lọ láti lọ pàdé wọn ó sì wí fún wọn pé, “Tí ẹ bá wá sọ́dọ̀ mi lálàáfíà, láti ràn mí lọ́wọ́ mo ṣetán láti mú un yín wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ṣùgbọ́n tí ẹ bá wá láti dá mi sí fún àwọn ọ̀tá mi nígbà tí ọwọ́ mi bá mọ́ kúrò nínú ìwà agbára, kí Ọlọ́run àwọn baba wa kí ó sì ri kí ó sì ṣe ìdájọ́.”
17 Davi saiu-lhes ao encontro e lhes disse: Se é como amigos que vindes a mim, para me prestar auxílio, eu estou unido de coração convosco; mas, se é para me trair e me entregar aos inimigos, enquanto minhas mãos estão limpas de toda violência, que o Deus de nossos pais o veja e faça justiça.
18 Nígbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ wa sórí Amasai ìjòyè àwọn ọgbọ̀n, ó sì wí pé,
18 Então o espírito entrou em Amasaí, chefe dos trinta, o qual disse: A ti, Davi, e contigo, filho de Isaí! Paz, paz a ti e àquele que te protege, porque teu Deus te presta auxílio. Davi recebeu-os e lhes deu um lugar entre os chefes do bando.
19 Díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin Manase sì yà sí ọ̀dọ̀ Dafidi nígbà tí ó lọ pẹ̀lú àwọn ará Filistini láti bá Saulu jà. (Òun àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wọn kò sì ran ará Filistini lọ́wọ́ nítorí, lẹ́yìn tiwọn sọ̀rọ̀ papọ̀, àwọn olórí wọn rán wọn jáde, wọ́n sì wí pé, “Yóò jẹ́ ìparun fún wa tí ó bá padà tọ ọ̀gá rẹ̀ Saulu lọ.”)
19 De Manassés também passaram homens para o lado de Davi, quando ele foi, com os filisteus, fazer guerra a Saul. Contudo, não socorreram os filisteus, porque, depois de se reunirem em conselho, os príncipes dos filisteus, despediram Davi, dizendo: Ele passará para o lado de seu mestre Saul, com perigo de nossas cabeças.
20 Nígbà tí Dafidi lọ sí Siklagi, àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin ti Manase ẹni tí ó sì yà sọ́dọ̀ rẹ̀. Adina, Josabadi, Jediaeli, Mikaeli, Josabadi, Elihu àti Siletai, àwọn olórí ìrẹ́pọ̀ ti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní Manase.
20 Quando voltou a Siceleg, homens de Manassés juntaram-se a ele: Ednas, Jozabad, Jediel, Miguel, Jozabad, Eliú e Salati, chefes de milhares de homens de Manassés.
21 Wọ́n sì ran Dafidi lọ́wọ́ lórí ẹgbẹ́ ogun náà, nítorí gbogbo wọn ni akọni ènìyàn àwọn sì tún ni olórí nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.
21 Ajudaram Davi contra os bandos de saqueadores, porque todos eram homens valentes, e foram chefes no exército.
22 Ọjọ́ dé ọjọ́ ni àwọn ọkùnrin wá láti ran Dafidi lọ́wọ́, títí tí ó fi ní àwọn ológun ńlá, bí ogun Ọlọ́run.
22 Todos os dias, vinham homens a Davi para auxiliá-lo, tanto que, por fim, ele teve um grande exército, como um exército de Deus.
23 Àwọn wọ̀nyí sì ni iye ọkùnrin tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun àwọn ẹni tí ó wá sọ́dọ̀ Dafidi ní Hebroni láti yí ìjọba Dafidi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.
23 Este é o número dos homens equipados para a guerra que foram ter com Davi, em Hebron, para transferir-lhe o reino de Saul, segundo a ordem do Senhor:
24 Ọkùnrin Juda, tí o ń gbé asà àti ọ̀kọ̀, ẹgbàáta lé lẹ́gbẹ̀rin (6,800) tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun.
24 filhos de Judá, portadores de escudo e lança: 6.800, armados para a guerra.
25 Àwọn ọkùnrin Simeoni, akọni tó mú fún ogun sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ó lé ọgọ́rùn-ún (7,100);
25 Dos filhos de Simeão, 7.100 valentes guerreiros.
26 àwọn ọkùnrin Lefi ẹgbàajì ó le ẹgbẹ̀ta (4,600),
26 Dos filhos de Levi, 4.600;
27 pẹ̀lú Jehoiada, olórí ìdílé Aaroni pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (3,700) ènìyàn,
27 Jojada, chefe da casa de Aarão, com 3.700 homens,
28 àti Sadoku akọni ọ̀dọ́mọkùnrin, pẹ̀lú àwọn méjìlélógún ìjòyè láti ọ̀dọ̀ àwọn ìdílé rẹ̀;
28 e Sadoc, jovem e valente guerreiro, e a casa de seu pai, 22 chefes.
29 àwọn arákùnrin Benjamini ìbátan ọkùnrin Saulu ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000), ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni tí ó si kù ní olóòtítọ́ sí ilé Saulu títí di ìgbà náà;
29 Dos filhos de Benjamim, irmãos de Saul, 3.000; pois, até então, a maior parte deles guardava fidelidade à casa de Saul.
30 àwọn arákùnrin Efraimu, ògbójú akọni, ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n nílé baba wọn ogún ẹgbẹ̀rún ó le ẹgbẹ̀rin (20,800);
30 Dos filhos de Efraim, 20.800 guerreiros conhecidos pela sua valentia nas suas famílias.
31 àwọn ọkùnrin nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Manase, tí a yàn nípa orúkọ láti wá àti láti yan Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba, ẹgbàá mẹ́sàn (18,000).
31 Da meia tribo de Manassés, 18.000, que foram nominalmente designados para ir proclamar Davi rei.
32 Àti ní ti àwọn ọmọ Isakari, àwọn ẹni tí ó ní òye àkókò, láti mọ ohun tí Israẹli ìbá máa ṣe; olórí wọn jẹ́ ìgbà; àti gbogbo àwọn ìbátan wọn ń bẹ ní ìkáwọ́ wọn.
32 Dos filhos de Issacar, que tinham o senso da oportunidade e sabiam o que Israel devia fazer, 200 chefes e todos os seus irmãos sob suas ordens.
33 Àwọn ọkùnrin Sebuluni, àti àwọn jagunjagun tí ó ti nípa ogun múra fún ogun pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ohun èlò ìjà, láti ran Dafidi lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò fi iyèméjì ṣe ìjólóòótọ́ wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (50,000).
33 De Zabulon, 50.000, em estado de ir para o exército, preparados para o combate, perfeitamente equipados com todas as armas, prontos para socorrer Davi, de coração resoluto.
34 Àwọn ọkùnrin Naftali, ẹgbẹ̀rún (1,000) ìjòyè àpapọ̀ pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún (36,000). Ọkùnrin tí wọ́n gbé asà àti ọ̀kọ̀ wọn.
34 De Neftali, 1.000 chefes e, com eles, 37.000 homens levando escudo e lança.
35 Àwọn ọkùnrin Dani, tí wọ́n ṣetán fún ogun ẹgbàá mẹ́tàlá (28,600).
35 Dos danitas, 28.600 homens, prontos para se pôr em linha de batalha.
36 Àwọn ọkùnrin Aṣeri, àwọn tí ó ti ní ìmọ̀ ogun múra fún ogun ọ̀kẹ́ méjì (40,000).
36 De Aser, aptos para o serviço militar e preparados para o combate, 40.000.
37 Láti ìlà-oòrùn Jordani, ọkùnrin Reubeni, Gadi, àti ìdajì ẹ̀yà Manase, dìmọ́ra pẹ̀lú gbogbo onírúurú ohun èlò ìjà ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000).
37 E, do outro lado do Jordão, dos rubenitas, dos gaditas e da meia tribo de Manassés, em perfeito equipamento de armas de guerra, 120.000.
38 Gbogbo èyí ni àwọn ọkùnrin ológun tí ó fi ara wọn fún ogun láti ṣe iṣẹ́ fún nínú ẹgbẹ́.
38 Todos esses homens de guerra, prontos para se formarem em linha de batalha, vieram de coração sincero a Hebron, para aclamar Davi rei de todo o Israel. E todo o restante de Israel estava igualmente unânime em aclamar Davi rei.
39 Àwọn ọkùnrin náà lo ọjọ́ mẹ́ta níbẹ̀ pẹ̀lú Dafidi, wọ́n jẹ, wọ́n sì ń mu, nítorí ìdílé wọn ti pèsè oúnjẹ fún wọn.
39 Permaneceram ali, três dias com Davi, comendo e bebendo, porque seus irmãos lhes tinham preparado víveres.
40 Àwọn aládùúgbò láti ọ̀nà jíjìn gẹ́gẹ́ bí Isakari, Sebuluni àti Naftali gbé oúnjẹ wá lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, lórí ràkunmí, àti lórí ìbáaka àti lórí màlúù, àní oúnjẹ ti ìyẹ̀fun, èso àjàrà gbígbẹ, èso ọ̀pọ̀tọ́, àkàrà dídùn, ọtí wáìnì, òróró, màlúù àti àgùntàn, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ wà ní Israẹli.
40 Ademais, os que moravam perto deles, até Issacar, Zabulon e Neftali, traziam-lhes víveres, sobre jumentos, camelos, mulas e bois, farinha, massa de figos, tortas de uvas, vinho, óleo, bois, ovelhas em abundância; porque havia alegria em Israel.
Atalhos do teclado
- Capítulo anterior←
- Próximo capítulo→
- Versículo anteriork
- Próximo versículoj
- Limpar seleçãoEsc
- Esta ajuda?
Estude este capítulo no WhatsApp
Peça à IA da Bíblia Fala para explicar 1 Crônicas 12, comparar traduções ou montar um estudo — tudo direto pelo WhatsApp.