Zacarias 3

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YOR) vs BKJ

Sair da comparação
1 Ó sì fi Joṣua olórí àlùfáà hàn mí, ó dúró níwájú angẹli Olúwa, Satani sí dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti kọjú ìjà sí i.
1 E ele me mostrou Josué, o sumo sacerdote, posicionado diante do anjo do SENHOR, e Satanás de pé, à sua direita para se lhe opor.
2 Olúwa si wí fún Satani pé, “Olúwa bá ọ wí ìwọ Satani; àní Olúwa tí ó ti yan Jerusalẹmu, bá ọ wí, igi iná kọ́ ni èyí tí a mú kúrò nínú iná?”
2 E o SENHOR disse a Satanás: O SENHOR te repreenda, ó Satanás; o SENHOR, que escolheu Jerusalém, te repreenda; não é este um tição tirado do fogo?
3 A sì wọ Joṣua ni aṣọ èérí, ó sì dúró níwájú angẹli náà.
3 Ora, Josué, vestido de roupas sujas, estava de pé diante do anjo.
4 Ó sì dáhùn ó wí fún àwọn tí ó dúró níwájú rẹ̀ pé, “Bọ́ aṣọ èérí nì kúrò ní ara rẹ̀.”
4 Então ele respondeu e falou aos que estavam diante dele, dizendo: Tirai estas roupas sujas dele. E a ele lhe disse: Eis que fiz a iniquidade passar de ti, e te vestirei com outra vestimenta.
5 Mó sì wí pé, “Jẹ kí wọn fi gèlè mímọ́ wé e lórí.” Wọn sì fi gèlè mímọ́ wé e lórí, wọn sì fi aṣọ wọ̀ ọ́. Angẹli Olúwa sì dúró tì í.
5 E eu disse: Coloquem uma mitra limpa sobre a sua cabeça. Então colocaram uma mitra limpa sobre a sua cabeça, e vestiram-no com trajes; e o anjo do SENHOR estava perto.
6 Angẹli Olúwa sì tẹnumọ́ ọn fún Joṣua pé:
6 E o anjo do SENHOR protestou a Josué, dizendo:
7 “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Bí ìwọ ọ́ bá rìn ní ọ̀nà mi, bí ìwọ yóò bá sì pa àṣẹ mi mọ́, ìwọ yóò sì ṣe ìdájọ́ ilé mi pẹ̀lú, ìwọ yóò sì ṣe àkóso ààfin mi, èmi yóò fún ọ ní ààyè láti rìn láàrín àwọn tí ó dúró yìí.
7 Assim diz o SENHOR dos Exércitos: Se andares nos meus caminhos, e se observares a minha ordenança, então tu também julgarás a minha casa, e também guardarás os meus átrios, e te darei lugar para andar entre esses que ficam aqui.
8 “ ‘Gbọ́, ìwọ Joṣua olórí àlùfáà, ìwọ, àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ tí ó jókòó níwájú rẹ: nítorí ẹni ìyanu ni wọ́n: nítorí kíyèsi i, èmi yóò mú ẹ̀ka náà wá fun ìránṣẹ́ mi.
8 Ouve, pois, ó Josué, sumo sacerdote, tu e os teus companheiros que se assentam diante de ti; porque são homens admiráveis; eis que eu farei vir o meu servo, o Renovo.
9 Nítorí kíyèsi i, òkúta tí mo tí gbé kalẹ̀ níwájú Joṣua; lórí òkúta kan ni ojú méje wà: kíyèsi i, èmi yóò fín àkọlé rẹ̀,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi yóò sì mú ẹ̀bi ilẹ̀ náà kúrò ní ọjọ́ kan.
9 Observai a pedra que coloquei diante de Josué; sobre uma pedra estarão sete olhos; eis que gravarei a sua inscrição, diz o SENHOR dos Exércitos, e removerei a iniquidade daquela terra em um só dia.
10 “ ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ní ọjọ́ náà ni olúkúlùkù yóò pe ẹnìkejì láti jókòó rẹ̀ sábẹ́ igi àjàrà àti sábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́.’ ”
10 Naquele dia, diz o SENHOR dos Exércitos, cada homem convidará o seu vizinho para debaixo da videira e para debaixo da figueira.

Ler em outra tradução

Comparar com outra

Estude este capítulo no WhatsApp

Peça à IA da Bíblia Fala para explicar Zacarias 3, comparar traduções ou montar um estudo — tudo direto pelo WhatsApp.