Levítico 26
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YOR) vs NAA
1 “ ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mọ ère òrìṣà, tàbí kí ẹ̀yin gbe ère kalẹ̀ tàbí kí ẹ̀yin gbẹ́ ère òkúta: kí ẹ̀yin má sì gbẹ́ òkúta tí ẹ̀yin yóò gbé kalẹ̀ láti sìn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
1 — Não façam ídolos para vocês, nem levantem imagem de escultura nem coluna, nem ponham pedra com figuras esculpidas na terra de vocês, para se inclinarem diante dela; porque eu sou o Senhor , o Deus de vocês.
2 “ ‘Ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́ kí ẹ̀yin sì bọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi. Èmi ni Olúwa.
2 Guardem os meus sábados e reverenciem o meu santuário. Eu sou o Senhor .
3 “ ‘Bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ẹ̀yin sì ṣọ́ra láti pa òfin mi mọ́.
3 — Se andarem nos meus estatutos, guardarem os meus mandamentos e os cumprirem,
4 Èmi yóò rọ̀jò fún yín ní àkókò rẹ̀, kí ilẹ̀ yín le mú èso rẹ̀ jáde bí ó tí yẹ kí àwọn igi eléso yín so èso.
4 então eu lhes darei as chuvas na época certa, a terra produzirá a sua colheita e a árvore do campo dará o seu fruto.
5 Èrè oko yín yóò pọ̀ dé bi pé ẹ ó máa pa ọkà títí di àsìkò ìkórè igi eléso, ẹ̀yin yóò sì máa gbé ní ilẹ̀ yín láìléwu.
5 A debulha dos grãos se estenderá até o tempo da vindima das uvas, e a vindima se estenderá até o tempo da sementeira. Vocês comerão o seu pão à vontade e habitarão em segurança na sua terra.
6 “ ‘Èmi yóò fún yín ní àlàáfíà ní ilẹ̀ yín, ẹ̀yin yóò sì sùn láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Èmi yóò mú kí gbogbo ẹranko búburú kúrò ní ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni idà kì yóò la ilẹ̀ yín já.
6 — Estabelecerei paz na terra. Vocês se deitarão, e não haverá quem os atemorize; afastarei da terra os animais nocivos, e pela terra de vocês não passará espada.
7 Ẹ̀yin yóò lé àwọn ọ̀tá yín, wọn yóò sì tipa idà kú.
7 Vocês perseguirão os seus inimigos, e eles cairão à espada diante de vocês.
8 Àwọn márùn-ún péré nínú yín yóò máa ṣẹ́gun ọgọ́rùn-ún ènìyàn, àwọn ọgọ́rùn-ún yóò sì máa ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000), àwọn ọ̀tá yín yóò tipa idà kú níwájú yín.
8 Cinco de vocês perseguirão cem deles, e cem de vocês perseguirão dez mil; e os seus inimigos cairão à espada diante de vocês.
9 “ ‘Èmi yóò fi ojúrere wò yín, Èmi yóò mú kí ẹ bí sí i, Èmi yóò jẹ́ kí ẹ pọ̀ sí i, Èmi yóò sì pa májẹ̀mú mi mọ́ pẹ̀lú yín.
9 Olharei para vocês, e os farei fecundos, e os multiplicarei, e confirmarei a minha aliança com vocês.
10 Àwọn èrè oko yín yóò pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin ó máa jẹ èrè ọdún tí ó kọjá, ẹ̀yin ó sì kó wọn jáde, kí ẹ̀yin lè rí ààyè kó tuntun sí.
10 Comerão o que tiver sobrado da colheita anterior e, para dar lugar à nova colheita, jogarão fora o que tiver sobrado da anterior.
11 Èmi yóò kọ́ àgọ́ mímọ́ mi sí àárín yín. Èmi kò sì ní kórìíra yín.
11 Porei o meu tabernáculo no meio de vocês e não me aborrecerei com vocês.
12 Èmi yóò wà pẹ̀lú yín, Èmi yóò máa jẹ́ Ọlọ́run yín, ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ènìyàn mi.
12 Andarei entre vocês e serei o seu Deus, e vocês serão o meu povo.
13 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, kí ẹ̀yin má ba à jẹ́ ẹrú fún wọn mọ́. Mo sì já ìdè àjàgà yín, mo sì mú kí ẹ̀yin máa rìn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a gbé lórí sókè.
13 Eu sou o Senhor , o Deus de vocês, que os tirei da terra do Egito, para que não fossem escravos dos egípcios; quebrei o jugo que pesava sobre vocês e os fiz andar de cabeça erguida.
14 “ ‘Bí ẹ̀yin kò bá fetí sí mi tí ẹ̀yin kò sì ṣe gbogbo òfin wọ̀nyí.
14 — Mas, se não me ouvirem e não cumprirem todos estes mandamentos;
15 Bí ẹ̀yin bá kọ àṣẹ mi tí ẹ̀yin sì kórìíra òfin mi, tí ẹ̀yin sì kùnà láti pa ìlànà mi mọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ sí májẹ̀mú mi.
15 se rejeitarem os meus estatutos, e se ficarem aborrecidos com os meus juízos, a ponto de não cumprirem todos os meus mandamentos, e quebrarem a minha aliança,
16 Èmi yóò ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí yín, Èmi yóò mú ìpayà òjijì bá yín: àwọn ààrùn afiniṣòfò, àti ibà afọ́nilójú, tí í pa ni díẹ̀díẹ̀. Ẹ̀yin yóò gbin èso ilẹ̀ yín lásán, nítorí pé àwọn ọ̀tá yín ni yóò jẹ gbogbo ohun tí ẹ̀yin ti gbìn.
16 então eu lhes farei isto: trarei sobre vocês pavor, fraqueza e febre, que fazem desaparecer o brilho dos olhos e definhar a vida. Vocês semearão os campos em vão, porque os seus inimigos ficarão com a colheita.
17 Èmi yóò dojúkọ yín títí tí ẹ̀yin ó fi di ẹni ìkọlù; àwọn tí ó kórìíra yín ni yóò sì ṣe àkóso lórí yín. Ìbẹ̀rù yóò mú yín dé bi pé ẹ̀yin yóò máa sá káàkiri nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé yín.
17 Voltarei o meu rosto contra vocês, e serão derrotados pelos seus inimigos. Aqueles que os odeiam dominarão sobre vocês, e vocês fugirão mesmo quando ninguém os estiver perseguindo.
18 “ ‘Bí ẹ̀yin kò bá wá gbọ́ tèmi lẹ́yìn gbogbo èyí, Èmi yóò fi kún ìyà yín ní ìlọ́po méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.
18 Se ainda assim não me ouvirem, tornarei a castigá-los sete vezes mais por causa dos seus pecados.
19 Èmi yóò fọ́ agbára ìgbéraga yín, ojú ọ̀run yóò le koko bí irin, ilẹ̀ yóò sì le bí idẹ (òjò kò ní rọ̀: ilẹ̀ yín yóò sì le).
19 Quebrarei o orgulho da força de vocês e farei com que os céus sejam como ferro e a terra de vocês seja como bronze.
20 Ẹ ó máa lo agbára yín lásán torí pé ilẹ̀ yín kì yóò so èso, bẹ́ẹ̀ ni àwọn igi yín kì yóò so èso pẹ̀lú.
20 Vocês gastarão as suas forças em vão; a terra não dará a sua colheita, e as árvores da terra não darão o seu fruto.
21 “ ‘Bí ẹ bá tẹ̀síwájú láì gbọ́ tèmi, Èmi yóò tún fa ìjayà yín le ní ìgbà méje gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ yín.
21 — E, se andarem em oposição a mim e não quiserem me ouvir, trarei sobre vocês pragas sete vezes piores, segundo os seus pecados.
22 Èmi yóò rán àwọn ẹranko búburú sí àárín yín, wọn yóò sì pa àwọn ọmọ yín, wọn yóò run agbo ẹran yín, díẹ̀ nínú yín ni wọn yóò ṣẹ́kù kí àwọn ọ̀nà yín lè di ahoro.
22 Porque enviarei para o meio de vocês animais selvagens, que os deixarão sem filhos, acabarão com o seu gado e os reduzirão a poucos; e as suas estradas ficarão desertas.
23 “ ‘Bí ẹ kò bá tún yípadà lẹ́yìn gbogbo ìjìyà wọ̀nyí, tí ẹ sì tẹ̀síwájú láti lòdì sí mi.
23 — Se ainda com isto vocês não se corrigirem e não voltarem para mim, porém andarem em oposição a mim,
24 Èmi náà yóò lòdì sí yín. Èmi yóò tún fa ìjìyà yín le ní ìlọ́po méje ju ti ìṣáájú.
24 eu também serei contrário a vocês e eu mesmo os ferirei sete vezes mais por causa dos seus pecados.
25 Èmi yóò mú idà wá bá yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín láti fi gbẹ̀san májẹ̀mú mi tí ẹ kò pamọ́. Bí ẹ ba sálọ sí ìlú yín fún ààbò, Èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín yín, àwọn ọ̀tá yín, yóò sì ṣẹ́gun yín.
25 Trarei sobre vocês a espada vingadora da minha aliança. E então, quando vocês se refugiarem nas suas cidades, enviarei a peste para o meio de vocês, e vocês serão entregues nas mãos do inimigo.
26 Èmi yóò dá ìpèsè oúnjẹ yín dúró, dé bi pé: inú ààrò kan ni obìnrin mẹ́wàá yóò ti máa se oúnjẹ yín. Òsùwọ̀n ni wọn yóò fi máa yọ oúnjẹ yín, ẹ ó jẹ ṣùgbọ́n, ẹ kò ní yó.
26 Quando eu lhes tirar o sustento do pão, dez mulheres poderão assar o pão de vocês num único forno e o repartirão por peso; vocês comerão, mas não conseguirão ficar satisfeitos.
27 “ ‘Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ kò bá gbọ́ tèmi, tí ẹ sì lòdì sí mi,
27 — Se ainda com isto não me ouvirem e andarem em oposição a mim,
28 ní ìbínú mi, èmi yóò korò sí yín, èmi tìkára mi yóò fìyà jẹ yín ní ìgbà méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.
28 eu também, com furor, serei contrário a vocês e os castigarei sete vezes mais por causa dos seus pecados.
29 Ebi náà yóò pa yín dé bi pé ẹ ó máa jẹ ẹran-ara àwọn ọmọ yín ọkùnrin, àti àwọn ọmọ yín obìnrin.
29 Terão de comer a carne de seus próprios filhos e filhas.
30 Èmi yóò wó àwọn pẹpẹ òrìṣà yín, lórí òkè níbi tí ẹ ti ń sìn, Èmi yóò sì kó òkú yín jọ, sórí àwọn òkú òrìṣà yín. Èmi ó sì kórìíra yín.
30 Destruirei os seus lugares altos, derrubarei os altares onde queimam incenso e amontoarei os seus cadáveres sobre o cadáver dos deuses que vocês adoram; a minha alma se aborrecerá com vocês.
31 Èmi yóò sọ àwọn ìlú yín di ahoro, èmi yóò sì ba àwọn ilé mímọ́ yín jẹ́. Èmi kì yóò sì gbọ́ òórùn dídùn yín mọ́.
31 Reduzirei as cidades de vocês a deserto, destruirei os santuários onde vocês adoram e não aspirarei o aroma agradável dos seus sacrifícios.
32 Èmi yóò pa ilẹ̀ yín run dé bi pé ẹnu yóò ya àwọn ọ̀tá yín tí ó bá gbé ilẹ̀ náà.
32 Assolarei a terra, e os inimigos de vocês, que nela vierem morar, ficarão espantados.
33 Èmi yóò sì tú yín ká sínú àwọn orílẹ̀-èdè, Èmi yóò sì yọ idà tì yín lẹ́yìn, ilẹ̀ yín yóò sì di ahoro, àwọn ìlú yín ni a ó sì parun.
33 Espalharei vocês entre as nações e irei atrás de vocês com a espada na mão; a terra de vocês será assolada, e as cidades ficarão em ruínas.
34 Ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi fún gbogbo ìgbà tí ẹ fi wà ní ilẹ̀ àjèjì tí ẹ kò fi lò ó. Ilẹ̀ náà yóò sinmi láti fi dípò ọdún tí ẹ kọ̀ láti fún un.
34 — Então a terra celebrará nos seus sábados, todos os dias da sua assolação, e vocês estarão na terra dos seus inimigos; nesse tempo, a terra descansará e observará os seus sábados.
35 Níwọ́n ìgbà tí ẹ kò lò ó, ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi tí kò ní lákòókò ìsinmi rẹ̀ lákokò tí ẹ fi ń gbé orí rẹ̀.
35 Durante todos os dias da assolação a terra descansará, porque não descansou nos sábados de vocês, quando vocês moravam nela.
36 “ ‘Èmi yóò jẹ́ kí ó burú fún àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ ìgbèkùn dé bi pé ìró ewé tí ń mì lásán yóò máa lé wọn sá. Ẹ ó máa sá bí ẹni tí ń sá fún idà. Ẹ ó sì ṣubú láìsí ọ̀tá láyìíká yín.
36 Aqueles de vocês que sobreviverem, eu lhes meterei no coração uma ansiedade tal, nas terras dos seus inimigos, que o ruído de uma folha movida os perseguirá; fugirão como quem foge da espada; e cairão sem ninguém os perseguir.
37 Wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn, bí ẹni tí ń sá fún idà nígbà tí kò sí ẹni tí ń lé yín. Ẹ̀yin kì yóò sì ní agbára láti dúró níwájú ọ̀tá yín.
37 Cairão uns sobre os outros como diante da espada, sem ninguém os perseguir; vocês não conseguirão se levantar diante dos seus inimigos.
38 Ẹ̀yin yóò ṣègbé láàrín àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà. Ilẹ̀ ọ̀tá yín yóò sì jẹ yín run.
38 Vocês perecerão entre as nações, e a terra dos seus inimigos os consumirá.
39 Àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú yín ni yóò ṣòfò dànù ní ilẹ̀ ọ̀tá yín torí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ti àwọn baba ńlá yín.
39 Aqueles de vocês que sobreviverem serão consumidos pela sua iniquidade nas terras dos inimigos de vocês e pela iniquidade de seus pais com eles serão consumidos.
40 “ ‘Bí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ti baba ńlá wọn, ìwà ìṣọ̀tẹ̀ wọn àti bí wọ́n ti ṣe lòdì sí mi.
40 — Mas, se eles confessarem a sua iniquidade e a iniquidade de seus pais, na infidelidade que cometeram contra mim, e se confessarem que andaram em oposição a mim,
41 Èyí tó mú mi lòdì sí wọn tí mo fi kó wọn lọ sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn. Nígbà tí wọ́n bá rẹ àìkọlà àyà wọn sílẹ̀ tí wọ́n bá sì gba ìbáwí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
41 fazendo com que também eu fosse contrário a eles e os fizesse entrar na terra dos seus inimigos; se o coração incircunciso que eles têm se humilhar, e aceitarem o castigo da sua iniquidade,
42 Nígbà náà ni Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Jakọbu àti pẹ̀lú Isaaki àti pẹ̀lú Abrahamu, Èmi yóò sì rántí ilẹ̀ náà.
42 então me lembrarei da minha aliança com Jacó, e também da minha aliança com Isaque, e também da minha aliança com Abraão, e da terra me lembrarei.
43 Àwọn ènìyàn náà yóò sì fi ilẹ̀ náà sílẹ̀, yóò sì ní ìsinmi rẹ̀ nígbà tí ó bá wà lófo láìsí wọn níbẹ̀. Wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé wọ́n kọ àwọn òfin mi. Wọ́n sì kórìíra àwọn àṣẹ mi.
43 Mas a terra na sua assolação, deixada por eles, folgará nos seus sábados; e eles aceitarão o castigo da sua iniquidade, visto que rejeitaram os meus juízos e se aborreceram com os meus estatutos.
44 Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, nígbà tí wọ́n bá wà nílé àwọn ọ̀tá wọn, èmi kì yóò ta wọ́n nù, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò kórìíra wọn pátápátá, èyí tí ó lè mú mi dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.
44 Mesmo assim, estando eles na terra de seus inimigos, não os rejeitarei, nem me aborrecerei com eles, para consumi-los e invalidar a minha aliança com eles, porque eu sou o Senhor , o Deus deles.
45 Nítorí wọn, èmi ó rántí májẹ̀mú mi tí mo ti ṣe pẹ̀lú baba ńlá wọn. Àwọn tí mo mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè láti jẹ́ Ọlọ́run wọn. Èmi ni Olúwa.’ ”
45 Pelo contrário, por amor deles, me lembrarei da aliança com os seus antepassados, que tirei da terra do Egito à vista das nações, para lhes ser por Deus. Eu sou o Senhor .
46 Ìwọ̀nyí ni òfin àti ìlànà tí Olúwa fún Mose ní orí òkè Sinai láàrín òun àti àwọn ọmọ Israẹli.
46 São estes os estatutos, juízos e leis que o Senhor estabeleceu entre si e os filhos de Israel, por meio de Moisés, no monte Sinai.
Atalhos do teclado
- Capítulo anterior←
- Próximo capítulo→
- Versículo anteriork
- Próximo versículoj
- Limpar seleçãoEsc
- Esta ajuda?
Estude este capítulo no WhatsApp
Peça à IA da Bíblia Fala para explicar Levítico 26, comparar traduções ou montar um estudo — tudo direto pelo WhatsApp.