Levítico 25
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YOR) vs ARA
1 Olúwa sọ fún Mose ní orí òkè Sinai pé,
1 Disse o Senhor a Moisés, no monte Sinai:
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún yín, ilẹ̀ náà gbọdọ̀ sinmi fún Olúwa.
2 Fala aos filhos de Israel e dize-lhes: Quando entrardes na terra, que vos dou, então, a terra guardará um sábado ao Senhor .
3 Ọdún mẹ́fà ni ìwọ ó fi gbin oko rẹ, ọdún mẹ́fà ni ìwọ ó fi tọ́jú ọgbà àjàrà rẹ, tí ìwọ ó sì fi kó èso wọn jọ.
3 Seis anos semearás o teu campo, e seis anos podarás a tua vinha, e colherás os seus frutos.
4 Ṣùgbọ́n ní ọdún keje kí ilẹ̀ náà ní ìsinmi: ìsinmi fún Olúwa. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ tọ́jú ọgbà àjàrà rẹ.
4 Porém, no sétimo ano, haverá sábado de descanso solene para a terra, um sábado ao Senhor ; não semearás o teu campo, nem podarás a tua vinha.
5 Ẹ má ṣe kórè ohun tí ó tìkára rẹ̀ hù, ẹ má ṣe kórè èso àjàrà ọgbà tí ẹ ò tọ́jú. Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ ní ìsinmi fún ọdún kan.
5 O que nascer de si mesmo na tua seara não segarás e as uvas da tua vinha não podada não colherás; ano de descanso solene será para a terra.
6 Ohunkóhun tí ilẹ̀ náà bá mú jáde ní ọdún ìsinmi ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún yín àní fún ẹ̀yin tìkára yín, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin yín, àwọn alágbàṣe àti àwọn tí ń gbé pẹ̀lú yín fún ìgbà díẹ̀.
6 Mas os frutos da terra em descanso vos serão por alimento, a ti, e ao teu servo, e à tua serva, e ao teu jornaleiro, e ao estrangeiro que peregrina contigo;
7 Fún àwọn ohun ọ̀sìn yín, àti àwọn ẹranko búburú ní ilẹ̀ yín. Ohunkóhun tí ilẹ̀ náà bá mú jáde ní ẹ lè jẹ.
7 e ao teu gado, e aos animais que estão na tua terra, todo o seu produto será por mantimento.
8 “ ‘Ọdún ìsinmi méje èyí tí í ṣe ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta (49) ni kí ẹ kà.
8 Contarás sete semanas de anos, sete vezes sete anos, de maneira que os dias das sete semanas de anos te serão quarenta e nove anos.
9 Lẹ́yìn náà, kí ẹ fọn fèrè ní gbogbo ibikíbi ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ní ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́. Ní ọjọ́ ètùtù yìí, ẹ fọn fèrè yíká gbogbo ilẹ̀ yín.
9 Então, no mês sétimo, aos dez do mês, farás passar a trombeta vibrante; no Dia da Expiação, fareis passar a trombeta por toda a vossa terra.
10 Ẹ ya àádọ́ta ọdún náà sọ́tọ̀ kí ẹ sì kéde òmìnira fún gbogbo ẹni tí ń gbé ilẹ̀ náà. Yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Kí olúkúlùkù padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀.
10 Santificareis o ano quinquagésimo e proclamareis liberdade na terra a todos os seus moradores; ano de jubileu vos será, e tornareis, cada um à sua possessão, e cada um à sua família.
11 Àádọ́ta ọdún ni yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Ẹ má ṣe gbin ohunkóhun, ẹ kò sì gbọdọ̀ kórè ohun tí ó hù fúnra rẹ̀ tàbí kí ẹ kórè ọgbà àjàrà tí ẹ kò dá.
11 O ano quinquagésimo vos será jubileu; não semeareis, nem segareis o que nele nascer de si mesmo, nem nele colhereis as uvas das vinhas não podadas.
12 Torí pé ọdún ìdásílẹ̀ ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún yín. Ẹ jẹ ohun tí ẹ mú jáde nínú oko náà.
12 Porque é jubileu, santo será para vós outros; o produto do campo comereis.
13 “ ‘Ní ọdún ìdásílẹ̀ yìí, kí olúkúlùkù gbà ohun ìní rẹ̀ padà.
13 Neste Ano do Jubileu, tornareis cada um à sua possessão.
14 “ ‘Bí ẹ bá ta ilẹ̀ fún ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín tàbí bí ẹ bá ra èyíkéyìí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ.
14 Quando venderes alguma coisa ao teu próximo ou a comprares da mão do teu próximo, não oprimas teu irmão.
15 Kí ẹ ra ilẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn yín ní gẹ́gẹ́ bí iye owó tí ó kù kí ọdún ìdásílẹ̀ pé, kí òun náà sì ta ilẹ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí iye ọdún rẹ̀ tókù láti kórè.
15 Segundo o número dos anos desde o Jubileu, comprarás de teu próximo; e, segundo o número dos anos das messes, ele venderá a ti.
16 Bí iye ọdún rẹ̀ bá gùn, kí iye owó rẹ̀ pọ̀, bí iye ọdún rẹ̀ bá kúrú, kí iye owó rẹ̀ kéré, torí pé ohun tí ó tà gan an ní iye èso rẹ̀.
16 Sendo muitos os anos, aumentarás o preço e, sendo poucos, abaixarás o preço; porque ele te vende o número das messes.
17 Ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ, ṣùgbọ́n ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
17 Não oprimais ao vosso próximo; cada um, porém, tema a seu Deus; porque eu sou o Senhor , vosso Deus.
18 “ ‘Ẹ tẹ̀lé àwọn ìlànà mi, kí ẹ sì kíyèsi láti pa òfin mi mọ́, kí ẹ ba à le máa gbé láìléwu ní ilẹ̀ náà.
18 Observai os meus estatutos, guardai os meus juízos e cumpri-os; assim, habitareis seguros na terra.
19 Nígbà yìí ni ilẹ̀ náà yóò so èso rẹ̀, ẹ ó sì jẹ àjẹyó, ẹ ó sì máa gbé láìléwu.
19 A terra dará o seu fruto, e comereis a fartar e nela habitareis seguros.
20 Ẹ le béèrè pé, “Kí ni àwa ó jẹ ní ọdún keje, bí a kò bá gbin èso tí a kò sì kórè?”
20 Se disserdes: Que comeremos no ano sétimo, visto que não havemos de semear, nem colher a nossa messe?
21 Èmi ó pèsè ìbùkún sórí yín tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ yín yóò so èso tó tó fún ọdún mẹ́ta lẹ́yìn rẹ̀.
21 Então, eu vos darei a minha bênção no sexto ano, para que dê fruto por três anos.
22 Bí ẹ bá gbin èso yín ní ọdún kẹjọ, àwọn èso ti tẹ́lẹ̀ ní ẹ ó máa jẹ, títí tí ìkórè ti ọdún kẹsànán yóò fi dé.
22 No oitavo ano, semeareis e comereis da colheita anterior até ao ano nono; até que venha a sua messe, comereis da antiga.
23 “ ‘Ẹ má ṣe ta ilẹ̀ yín ní àtàpa torí pé ẹ̀yin kọ́ lẹ ni ín, ti Ọlọ́run ni, ẹ̀yin jẹ́ àjèjì àti ayálégbé.
23 Também a terra não se venderá em perpetuidade, porque a terra é minha; pois vós sois para mim estrangeiros e peregrinos.
24 Ní gbogbo orílẹ̀-èdè ìní yín, ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìràpadà ilẹ̀ náà.
24 Portanto, em toda a terra da vossa possessão dareis resgate à terra.
25 “ ‘Bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín bá tálákà, dé bi pé ó ta ara àwọn ẹrù rẹ̀, kí ará ilé rẹ̀ tí ó súnmọ́ ọ ra ohun tí ó tà padà.
25 Se teu irmão empobrecer e vender alguma parte das suas possessões, então, virá o seu resgatador, seu parente, e resgatará o que seu irmão vendeu.
26 Ẹni tí kò ní ẹni tó lè rà á padà fún un, tí òun fúnra rẹ̀ sì ti lọ́rọ̀, tí ó sì ní ànító láti rà á.
26 Se alguém não tiver resgatador, porém vier a tornar-se próspero e achar o bastante com que a remir,
27 Kí ó mọ iye owó tí ó jẹ fún iye ọdún tí ó tà á, kí ó dá iye tí ó kù padà fún ẹni tí ó tà á fún, lẹ́yìn náà, ó lè padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.
27 então, contará os anos desde a sua venda, e o que ficar restituirá ao homem a quem vendeu, e tornará à sua possessão.
28 Ṣùgbọ́n bí kò bá rí ọ̀nà àti san án padà fún un. Ohun tí ó tà wà ní ìkáwọ́ ẹni tí ó rà á títí di ọdún ìdásílẹ̀. Kí ó dá a padà fún ẹni tí ó ni i ní ọdún ìdásílẹ̀, ẹni tí ó ni í tẹ́lẹ̀ lè tún padà gbà ohun ìní rẹ̀.
28 Mas, se as suas posses não lhe permitirem reavê-la, então, a que for vendida ficará na mão do comprador até ao Ano do Jubileu; porém, no Ano do Jubileu, sairá do poder deste, e aquele tornará à sua possessão.
29 “ ‘Bí arákùnrin kan bá ta ilé gbígbé kan ní ìlú olódi, kí ó rà á padà ní ìwọ̀n ọdún kan sí àkókò tí ó tà á, ní ìwọ̀n ọdún kan ni kí ó rà á padà.
29 Quando alguém vender uma casa de moradia em cidade murada, poderá resgatá-la dentro de um ano a contar de sua venda; durante um ano, será lícito o seu resgate.
30 Ṣùgbọ́n bí kò bá rà á padà láàrín ọdún náà ilé náà tí ó wà láàrín ìlú ni kí ó yọ̀ǹda pátápátá fún ẹni tí ó rà á, àti àwọn ìdílé rẹ̀. Kí wọ́n má da padà ní ọdún ìdásílẹ̀.
30 Se, passando-se-lhe um ano, não for resgatada, então, a casa que estiver na cidade que tem muro ficará em perpetuidade ao que a comprou, pelas suas gerações; não sairá do poder dele no Jubileu.
31 Ṣùgbọ́n àwọn ilé tí ó wà ní abúlé láìní odi ni kí a kà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ oko, a lè rà wọ́n padà, kí wọ́n sì da padà ní ọdún ìdásílẹ̀.
31 Mas as casas das aldeias que não têm muro em roda serão estimadas como os campos da terra; para elas haverá resgate, e sairão do poder do comprador no Jubileu.
32 “ ‘Àwọn ọmọ Lefi ní ẹ̀tọ́, nígbàkígbà láti ra ilẹ̀ wọn, tí ó jẹ́ ohun ìní wọn ní àwọn ìlú tí ó jẹ́ ti ọmọ Lefi.
32 Mas, com respeito às cidades dos levitas, às casas das cidades da sua possessão, terão direito perpétuo de resgate os levitas.
33 Torí náà ohun ìní àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n rà padà, fún àpẹẹrẹ, èyí ni pé ilẹ̀ tí a bá tà ní ìlúkílùú tí ó jẹ́ tiwọn, ó sì gbọdọ̀ di dídápadà ní ọdún ìdásílẹ̀, torí pé àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní ìlú àwọn Lefi ni ìní wọn láàrín àwọn ará Israẹli.
33 Se o levita não resgatar a casa que vendeu, então, a casa comprada na cidade da sua possessão sairá do poder do comprador, no Jubileu; porque as casas das cidades dos levitas são a sua possessão no meio dos filhos de Israel.
34 Ṣùgbọ́n ilẹ̀ tí wọ́n ti ń da ẹran tí ó jẹ́ ti ìlú wọn, wọn kò gbọdọ̀ tà wọ́n, ilẹ̀ ìní wọn láéláé ni.
34 Mas o campo no arrabalde das suas cidades não se venderá, porque lhes é possessão perpétua.
35 “ ‘Bí arákùnrin yín kan bá tálákà tí kò sì le è pèsè fún àìní ara rẹ̀, ẹ pèsè fún un bí ẹ ti ń ṣe fún àwọn àlejò tàbí àwọn tí ẹ gbà sílé: kí ó ba à le è máa gbé láàrín yín.
35 Se teu irmão empobrecer, e as suas forças decaírem, então, sustentá-lo-ás. Como estrangeiro e peregrino ele viverá contigo.
36 Ẹ kò gbọdọ̀ gba èlé kankan lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ bẹ̀rù Olúwa kí arákùnrin yín le è máa gbé láàrín yín.
36 Não receberás dele juros nem ganho; teme, porém, ao teu Deus, para que teu irmão viva contigo.
37 Ẹ má ṣe gba èlé lórí owó tí ẹ yá a bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ èrè lórí oúnjẹ tí ẹ tà fún un.
37 Não lhe darás teu dinheiro com juros, nem lhe darás o teu mantimento por causa de lucro.
38 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti láti fún yín ní ilẹ̀ Kenaani àti láti jẹ́ Ọlọ́run yín.
38 Eu sou o Senhor , vosso Deus, que vos tirei da terra do Egito, para vos dar a terra de Canaã e para ser o vosso Deus.
39 “ ‘Bí arákùnrin yín kan bá tálákà dé bi pé ó ta ara rẹ̀ fún ọ bí ẹrú. Má ṣe lò ó bí ẹrú.
39 Também se teu irmão empobrecer, estando ele contigo, e vender-se a ti, não o farás servir como escravo.
40 Jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ rẹ bí alágbàṣe tàbí àlejò láàrín yín, kí ó máa ṣiṣẹ́ sìn ọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀.
40 Como jornaleiro e peregrino estará contigo; até ao Ano do Jubileu te servirá;
41 Nígbà náà ni kí ó yọ̀ǹda òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọ́n padà sí ìdílé wọn àti sí ilẹ̀ ìní baba wọn.
41 então, sairá de tua casa, ele e seus filhos com ele, e tornará à sua família e à possessão de seus pais.
42 Torí pé ìránṣẹ́ mi ni àwọn ará Israẹli jẹ́. Ẹni tí mo mú jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, torí èyí ẹ kò gbọdọ̀ tà wọ́n lẹ́rú.
42 Porque são meus servos, que tirei da terra do Egito; não serão vendidos como escravos.
43 Ẹ má ṣe rorò mọ́ wọn: ṣùgbọ́n ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run yín.
43 Não te assenhorearás dele com tirania; teme, porém, ao teu Deus.
44 “ ‘Àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín lè jẹ́ láti orílẹ̀-èdè tí ó yí yín ká, ẹ lè ra àwọn ẹrú wọ̀nyí lọ́wọ́ wọn.
44 Quanto aos escravos ou escravas que tiverdes, virão das nações ao vosso derredor; delas comprareis escravos e escravas.
45 Bákan náà, ẹ sì le è ra àwọn àlejò tí ń gbé láàrín yín, àti àwọn ìdílé wọn tí a bí sáàrín yín. Wọn yóò sì di ohun ìní yín.
45 Também os comprareis dos filhos dos forasteiros que peregrinam entre vós, deles e das suas famílias que estiverem convosco, que nasceram na vossa terra; e vos serão por possessão.
46 Ẹ lè fi wọ́n sílẹ̀ bí ogún fún àwọn ọmọ yín, wọ́n sì lè sọ wọ́n di ẹrú títí láé. Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rorò mọ́ ọmọ Israẹli kankan.
46 Deixá-los-eis por herança para vossos filhos depois de vós, para os haverem como possessão; perpetuamente os fareis servir, mas sobre vossos irmãos, os filhos de Israel, não vos assenhoreareis com tirania, um sobre os outros.
47 “ ‘Bí àlejò kan láàrín yín tàbí ẹni tí ń gbé àárín yín fún ìgbà díẹ̀ bá lọ́rọ̀ tí ọmọ Israẹli sì tálákà dé bi pé ó ta ara rẹ̀ lẹ́rú fún àlejò tàbí ìdílé àlejò náà.
47 Quando o estrangeiro ou peregrino que está contigo se tornar rico, e teu irmão junto dele empobrecer e vender-se ao estrangeiro, ou peregrino que está contigo, ou a alguém da família do estrangeiro,
48 Ó lẹ́tọ̀ọ́ si ki a rà á padà lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ta ara rẹ̀. Ọ̀kan nínú ìbátan rẹ̀ le è rà á padà.
48 depois de haver-se vendido, haverá ainda resgate para ele; um de seus irmãos poderá resgatá-lo:
49 Àbúrò baba rẹ̀ ọkùnrin tàbí àbúrò rẹ̀ obìnrin tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá tan nínú ìdílé rẹ̀ le è rà wọ̀n padà. Bí ó bá sì ti lọ́rọ̀, ó lè ra ara rẹ̀ padà.
49 seu tio ou primo o resgatará; ou um dos seus, parente da sua família, o resgatará; ou, se lograr meios, se resgatará a si mesmo.
50 Kí òun àti olówó rẹ̀ ka iye ọdún tí ó ta ara rẹ̀ títí dé ọdún ìdásílẹ̀ kí iye owó ìdásílẹ̀ rẹ̀ jẹ́ iye tí wọ́n ń san lórí alágbàṣe fún iye ọdún náà.
50 Com aquele que o comprou acertará contas desde o ano em que se vendeu a ele até ao Ano do Jubileu; o preço da sua venda será segundo o número dos anos, conforme se paga a um jornaleiro.
51 Bí iye ọdún rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù bá pọ̀, kí iye owó fún ìràpadà rẹ̀ pọ̀.
51 Se ainda faltarem muitos anos, devolverá proporcionalmente a eles, do dinheiro pelo qual foi comprado, o preço do seu resgate.
52 Bí ó bá sì ṣe pé kìkì ọdún díẹ̀ ni ó kù títí di ọdún jubili, kí ó ṣe ìṣirò rẹ̀, kí ó sì san owó náà bí iye ìṣirò rẹ̀ padà.
52 Se restarem poucos anos até ao Ano do Jubileu, então, fará contas com ele e pagará, em proporção aos anos restantes, o preço do seu resgate.
53 Bí ẹ ti ń ṣe sí i lọ́dọọdún, ẹ rí i dájú pé olówó rẹ̀ kò korò mọ́ ọ.
53 Como jornaleiro, de ano em ano, estará com ele; não se assenhoreará dele com tirania à tua vista.
54 “ ‘Bí a kò bá rà á padà nínú gbogbo ọ̀nà wọ̀nyí, kí ẹ tú òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ ní ọdún ìdásílẹ̀.
54 Se desta sorte se não resgatar, sairá no Ano do Jubileu, ele e seus filhos com ele.
55 Nítorí pé ìránṣẹ́ ni àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ fún mi. Ìránṣẹ́ mi ni wọ́n, tí mo mú jáde láti Ejibiti wá. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
55 Porque os filhos de Israel me são servos; meus servos são eles, os quais tirei da terra do Egito. Eu sou o Senhor , vosso Deus.
Atalhos do teclado
- Capítulo anterior←
- Próximo capítulo→
- Versículo anteriork
- Próximo versículoj
- Limpar seleçãoEsc
- Esta ajuda?
Estude este capítulo no WhatsApp
Peça à IA da Bíblia Fala para explicar Levítico 25, comparar traduções ou montar um estudo — tudo direto pelo WhatsApp.