Levítico 18

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YOR) vs VC

Sair da comparação
VC Versão Católica
1 Olúwa sọ fún Mose pé:
1 O Senhor disse a Moisés:
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
2 "Dize aos israelitas o seguinte: eu sou o Senhor, vosso Deus.
3 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní Ejibiti níbi tí ẹ ti gbé rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Kenaani níbi tí èmi ń mú yín lọ. Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìṣe wọn.
3 Não procedereis conforme os costumes do Egito onde habitastes, ou de Canaã aonde vos conduzi: não seguireis seus costumes.
4 Kí ẹ̀yin kí ó sì máa ṣe òfin mi, kí ẹ̀yin sì máa pa ìlànà mi mọ́, láti máa rìn nínú wọn, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
4 Praticareis meus preceitos e observareis minhas leis, e a elas obedecereis. Eu sou o Senhor, vosso Deus.
5 Ẹ̀yin ó sì máa pa ìlànà mi mọ́ àti òfin mi; Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn. Èmi ni Olúwa.
5 Observareis meus preceitos e minhas leis: o homem que o observar viverá por eles. Eu sou o Senhor.
6 “ ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ súnmọ́ ìbátan rẹ̀ láti bá a lòpọ̀. Èmí ni Olúwa.
6 Nenhum de vós se achegará àquela que lhe é próxima por sangue, para descobrir sua nudez. Eu sou o Senhor.
7 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù baba rẹ nípa bíbá ìyá rẹ lòpọ̀, ìyá rẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ bá a lòpọ̀.
7 Não descobrirás a nudez de teu pai, nem a de tua mãe. Ela é tua mãe: não descobrirás a sua nudez.
8 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù baba rẹ nípa bíbá ìyàwó baba rẹ lòpọ̀, nítorí ìhòhò baba rẹ ni.
8 Não descobrirás a nudez da mulher de teu pai: é a nudez de teu pai.
9 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin rẹ tí ó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ lòpọ̀, yálà a bí i nílé yín tàbí lóde.
9 Nem a de tua irmã, filha de teu pai ou de tua mãe, nascida na casa ou fora dela.
10 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin, ọmọ rẹ ọkùnrin lòpọ̀ tàbí ọmọbìnrin ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀ nítorí pé ìhòhò wọn, ìhòhò ìwọ fúnra rẹ̀ ni.
10 Não descobrirás a nudez da filha de teu filho ou da filha de tua filha, porque é tua nudez.
11 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin aya baba rẹ lòpọ̀; èyí tí a bí fún baba rẹ nítorí pé arábìnrin rẹ ni.
11 Nem a da filha da mulher de teu pai, nascida de teu pai: é tua irmã.
12 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin baba rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan baba rẹ ni.
12 Não descobrirás a nudez da irmã de teu pai: ela é da mesma carne que teu pai.
13 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin màmá rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan ìyá rẹ ni.
13 Nem a da irmã de tua mãe; porque ela é da mesma carne que tua mãe.
14 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù arákùnrin baba rẹ nípa sísún mọ́ aya rẹ̀ láti bá a lòpọ̀ nítorí pé ìyàwó ẹ̀gbọ́n baba rẹ ni.
14 Não descobrirás a nudez do irmão de teu pai, aproximando-te de sua mulher: é tua tia.
15 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọ àna obìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé aya ọmọ rẹ ni. Má ṣe bá a lòpọ̀.
15 Não descobrirás a nudez de tua nora: é a mulher de teu filho. Não descobrirás, pois, a sua nudez.
16 “ ‘Má ṣe bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ ọkùnrin lòpọ̀ nítorí pé yóò tàbùkù ẹ̀gbọ́n rẹ.
16 Nem a da mulher de teu irmão: é a nudez de teu irmão.
17 “ ‘Má ṣe bá ìyá àti ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin ọmọbìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan rẹ tímọ́tímọ́ ni: nítorí àbùkù ni.
17 Não descobrirás a nudez de uma mulher e de sua filha, e não tomarás a filha de seu filho, nem a filha de sua filha, para descobrir a sua nudez: elas são tuas próximas parentas, e isso seria um crime.
18 “ ‘Má ṣe fẹ́ àbúrò ìyàwó rẹ obìnrin ní aya gẹ́gẹ́ bí orogún tàbí bá a lòpọ̀, nígbà tí ìyàwó rẹ sì wà láààyè.
18 Não tomarás a irmã de tua mulher, de modo que lhe seja um rival, descobrindo a sua nudez com a de tua mulher durante a sua vida.
19 “ ‘Má ṣe súnmọ́ obìnrin láti bá a lòpọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù, nítorí àkókò àìmọ́ ni.
19 Não te achegarás a uma mulher durante a sua menstruação para descobrir a sua nudez.
20 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá aya aládùúgbò rẹ lòpọ̀, kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́ pẹ̀lú rẹ̀.
20 Não terás comércio com a mulher de teu próximo: contaminar-te-ias com ela.
21 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ rú ẹbọ lórí pẹpẹ sí òrìṣà Moleki, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni Olúwa.
21 Não darás nenhum de teus filhos para ser sacrificado a Moloc; e não profanarás o nome de teu Deus. Eu sou o Senhor.
22 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọkùnrin lòpọ̀ bí ìgbà tí ènìyàn ń bá obìnrin lòpọ̀: ìríra ni èyí jẹ́.
22 Não te deitarás com um homem, como se fosse mulher: isso é uma abominação.
23 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ẹranko lòpọ̀ kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́. Obìnrin kò sì gbọdọ̀ jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹranko láti bá a lòpọ̀, ohun tó lòdì ni.
23 Não terás comércio com um animal, para te contaminares com ele. Uma mulher não se prostituirá a um animal: isso é uma abominação.
24 “ ‘Má ṣe fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ba ara rẹ jẹ́, torí pé nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé kúrò níwájú yín ti ba ara wọn jẹ́.
24 Não vos contamineis com nenhuma dessas coisas, porque é assim que se contaminaram as nações que vou expulsar diante de vós.
25 Nítorí pé ilẹ̀ náà di àìmọ́ nítorí náà mo fi ìyà jẹ ẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ilẹ̀ náà sì pọ àwọn olùgbé ibẹ̀ jáde.
25 A terra está contaminada; punirei suas iniqüidades e a terra vomitará seus habitantes.
26 Ṣùgbọ́n kí ẹ máa pa àṣẹ àti òfin mi mọ́. Onílé tàbí àjèjì tó ń gbé láàrín yín kò gbọdọ̀ ṣe ọ̀kan nínú àwọn ohun ìríra wọ̀nyí.
26 Vós, porém, observareis minhas leis e minhas ordens, e não cometereis nenhuma dessas abominações, tanto o aborígine como o estrangeiro que habita no meio de vós,
27 Nítorí pé gbogbo ohun ìríra wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ti gbé ilẹ̀ náà ṣáájú yín ti ṣe tí ó sì mú kí ilẹ̀ náà di aláìmọ́.
27 porque todas essas abominações cometeram os habitantes da terra que vos precederam, e a terra está contaminada.
28 Bí ẹ bá sọ ilẹ̀ náà di àìmọ́ yóò pọ̀ yín jáde bí ó ti pọ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti wá ṣáájú yín jáde.
28 Desse modo a terra não vos vomitará por havê-la contaminado, como vomitou os povos que a habitaram antes de vós.
29 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ohun ìríra wọ̀nyí, kí ẹ gé irú ẹni náà kúrò láàrín àwọn ènìyàn.
29 Todos aqueles, com efeito, que cometerem qualquer dessas abominações, serão cortados do meio de seu povo.
30 Nítorí náà ẹ gbọdọ̀ ṣe ohun tí mo fẹ́, kí ẹ má sì lọ́wọ́ nínú àṣà ìríra wọ̀nyí, tí wọn ń ṣe kí ẹ tó dé. Ẹ má ṣe fi wọ́n ba ara yín jẹ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”
30 Guardareis, pois, os meus mandamentos, e não seguireis nenhum dos costumes abomináveis que se praticavam antes de vós, e não vos contaminareis por eles. Eu sou o Senhor, vosso Deus."

Ler em outra tradução

Comparar com outra

Estude este capítulo no WhatsApp

Peça à IA da Bíblia Fala para explicar Levítico 18, comparar traduções ou montar um estudo — tudo direto pelo WhatsApp.