Levítico 11
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YOR) vs VC
1 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,
1 O senhor disse a Moisés e a Aarão: "Dize aos israelitas o seguinte:
2 “Ẹ sọ fún àwọn ara Israẹli pé, ‘Nínú gbogbo ẹranko tí ń gbé lórí ilẹ̀, àwọn wọ̀nyí ni ẹ le jẹ.
2 entre todos os animais da terra, eis o que podereis comer:
3 Gbogbo ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ bá là tí ó sì ń jẹ àpọ̀jẹ.
3 podereis comer todo animal que tem a unha fendida e o casco dividido, e que rumina.
4 “ ‘Àwọn mìíràn wà tó ń jẹ àpọ̀jẹ nìkan. Àwọn mìíràn wà tó jẹ́ pé pátákò ẹsẹ̀ wọn nìkan ni ó là, ìwọ̀nyí ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ fún àpẹẹrẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbákasẹ ń jẹ àpọ̀jẹ kò ya pátákò ẹsẹ̀, àìmọ́ ni èyí jẹ́.
4 Mas não comereis aqueles que só ruminam ou só têm a unha fendida. A estes, tê-los-eis por impuros: tal como o camelo, que rumina mas não tem o casco fendido.
5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gara (ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta) ń jẹ àpọ̀jẹ; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín.
5 E como o coelho igualmente, que rumina mas não tem a unha fendida; tê-los-eis por impuros.
6 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ehoro ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n kò ya pátákò ẹsẹ̀; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín.
6 E como a lebre também, que rumina, mas não tem a unha fendida; tê-la-eis por impura,
7 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́dẹ̀ ya pátákò ẹsẹ̀ ṣùgbọ́n kì í jẹ àpọ̀jẹ; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín.
7 E enfim, como o porco, que tem a unha fendida e o pé dividido, mas não rumina; tê-lo-eis por impuro.
8 Ẹ má ṣe jẹ ẹran wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn. Àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.
8 Não comereis da sua carne e não tocareis nos seus cadáveres: vós os tereis por impuros.
9 “ ‘Nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá tí ń gbé inú omi Òkun, àti nínú odò: èyíkéyìí tí ó bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́ ni ẹ lè jẹ́.
9 Entre os animais que vivem na água, eis que podereis comer: podereis comer tudo o que tem barbatanas e escamas, nas águas, no mar e nos rios.
10 Ṣùgbọ́n nínú gbogbo ẹ̀dá tí ń gbé inú òkun àti nínú odò tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́, yálà nínú gbogbo àwọn tí ń rákò tàbí láàrín gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè yòókù tí ń gbé inú omi àwọn ni kí ẹ kórìíra.
10 Mas tereis em abominação todos os que não têm barbatanas nem escama, nos mares e nos rios, entre todos os animais que vivem nas águas e entre todos os seres vivos que nelas se encontram.
11 Nígbà tí ẹ ti kórìíra wọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn: ẹ gbọdọ̀ kórìíra òkú wọn.
11 A estes, tê-los-eis em abominação: não comereis de sua carne e tereis em abominação os seus cadáveres.
12 Ohunkóhun tí ń gbé inú omi tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́ gbọdọ̀ jásí ìríra fún yín.
12 Todos os que nas águas não têm barbatanas nem escamas, tê-los-eis em abominação.
13 “ ‘Àwọn ẹyẹ wọ̀nyí ni ẹ gbọdọ̀ kórìíra tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n torí pé ohun ìríra ni wọ́n: idì, oríṣìíríṣìí igún,
13 "Entre as aves, eis as que tereis abominação e de cuja carne não comereis, porque é uma abominação:
14 àwòdì àti onírúurú àṣá,
14 a águia, o falcão e o abutre, o milhafre e toda variedade de falcões,
15 onírúurú ẹyẹ ìwò,
15 toda espécie de corvo,
16 Òwìwí, onírúurú ògòǹgò, onírúurú ẹ̀lúùlú, onírúurú àwòdì,
16 a avestruz, a andorinha, a gaivota e toda espécie de gavião,
17 Òwìwí kéékèèké, onírúurú òwìwí,
17 o mocho, a coruja e o íbis,
18 Òwìwí funfun àti òwìwí ilẹ̀ pápá, àti àkàlà,
18 o cisne, o pelicano, o alcatraz
19 àkọ̀, onírúurú òòdẹ̀, atọ́ka àti àdán.
19 e a cegonha, toda variedade de garça, a poupa e o morcego.
20 “ ‘Gbogbo kòkòrò tí ń fò tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn ni wọ́n jẹ́ ìríra fún yín,
20 Todo volátil que anda sobre quatro pés vos será uma abominação.
21 irú àwọn kòkòrò oniyẹ̀ẹ́ tí wọn sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn tí ẹ le jẹ nìyí, àwọn kòkòrò tí wọ́n ní ìṣẹ́po ẹsẹ̀ láti máa fi fò lórí ilẹ̀.
21 Todavia, entre os insetos voláteis que andam sobre quatro pés podereis comer aqueles que, além de seus quatro pés, têm pernas para saltar em cima da terra.
22 Nínú àwọn wọ̀nyí ni ẹ lè jẹ onírúurú eṣú, onírúurú ìrẹ̀ àti onírúurú tata.
22 Eis, pois, os que podereis comer: toda espécie de gafanhotos, assim como as variedades de solam, de hargol e de hagab.
23 Ṣùgbọ́n gbogbo ohun ìyókù tí ń fò, tí ń rákò, tí ó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin, òun ni kí ẹ̀yin kí ó kà sí ìríra fún yín.
23 Qualquer outro volátil que tenha quatro pés vos será uma abominação.
24 “ ‘Nípa àwọn wọ̀nyí ni ẹ le fi sọ ara yín di àìmọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
24 Tornar-vos-eis imundos se os tocardes: se alguém tocar os seus cadáveres será impuro até a tarde,
25 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
25 e aquele que levar os seus cadáveres lavará suas vestes e será impuro até a tarde.
26 “ ‘Àwọn ẹranko tí pátákò wọn kò là tan tàbí tí wọn kò jẹ àpọ̀jẹ jẹ́ àìmọ́ fún yín. Ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú èyíkéyìí nínú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́.
26 Tereis por impuro todo animal que tenha a unha fendida, mas que não tem o pé dividido e não rumina; se alguém o tocar será imundo.
27 Nínú gbogbo ẹranko tí ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, àwọn tí ń fi èékánná wọn rìn jẹ́ aláìmọ́ fún yín, ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
27 Tereis também por impuros todos os quadrúpedes que andam nas plantas dos pés; se alguém tocar seus cadáveres será impuro até a tarde;
28 Ẹni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Wọ̀nyí jẹ́ àìmọ́ fún yín.
28 e aquele que levar os seus cadáveres lavará suas vestes e será impuro até a tarde. Tereis esses animais por impuros.
29 “ ‘Nínú gbogbo ẹranko tí ń rìn lórí ilẹ̀ ìwọ̀nyí ni ó jẹ́ àìmọ́ fún yín: Asé, eku àti oríṣìíríṣìí aláǹgbá,
29 Entre os animais que se movem em cima da terra, eis os que tereis por impuro: a toupeira, o rato e toda variedade de lagartos,
30 Ọmọnílé, alágẹmọ, aláǹgbá, ìgbín àti ọ̀gà.
30 o musaranho, a rã, a tartaruga, a lagartixa e o camaleão.
31 Nínú gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ìwọ̀nyí jẹ́ àìmọ́ fún yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
31 Tais são os répteis que tereis por impuros, quem os tocar mortos será impuro até a tarde.
32 Bí ọ̀kan nínú wọn bá kú tí wọ́n sì bọ́ sórí nǹkan kan, bí ó ti wù kí irú ohun náà wúlò tó, yóò di aláìmọ́ yálà aṣọ ni a fi ṣe é ni tàbí igi, irun aṣọ tàbí àpò, ẹ sọ ọ́ sínú omi yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ lẹ́yìn náà ni yóò tó di mímọ́.
32 Todo objeto o qual caírem os seus cadáveres será impuro: vasos de madeira, vestes, peles, sacos e qualquer outro utensílio. Por-se-á esse objeto na água e ele será imundo até a tarde; depois disso será puro.
33 Bí èyíkéyìí nínú wọn bá bọ́ sínú ìkòkò amọ̀, gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀ ti di àìmọ́. Ẹ gbọdọ̀ fọ ìkòkò náà.
33 Se cair uma parte desses cadáveres num vaso de terra, tudo o que se encontrar nele será impuro, e quebrareis esse vaso.
34 Bí omi inú ìkòkò náà bá dà sórí èyíkéyìí nínú oúnjẹ tí ẹ̀ ń jẹ oúnjẹ náà di aláìmọ́. Gbogbo ohun mímu tí a lè mú jáde láti inú rẹ̀ di àìmọ́.
34 Todo alimento preparado com água {desse vaso} será impuro; toda bebida, seja qual for o recipiente que a contenha, será impura.
35 Gbogbo ohun tí èyíkéyìí nínú òkú wọn bá já lé lórí di àìmọ́. Yálà ààrò ni tàbí ìkòkò ìdáná wọn gbọdọ̀ di fífọ́. Wọ́n jẹ́ àìmọ́. Ẹ sì gbọdọ̀ kà wọ́n sí àìmọ́.
35 Todo objeto sobre o qual cair alguma coisa dos seus cadáveres será impuro; o forno e o fogão serão destruídos: serão impuros, e vós os tereis como tais.
36 Bí òkú wọn bá bọ́ sínú omi tàbí kànga tó ní omi nínú, omi náà kò di aláìmọ́ ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá yọ òkú wọn jáde tí ó fi ọwọ́ kàn án yóò di aláìmọ́.
36 Contudo, as fontes e as cisternas em que há depósito de água ficarão puras, mas aquele que tocar os cadáveres será impuro.
37 Bí òkú ẹranko wọ̀nyí bá bọ́ sórí ohun ọ̀gbìn tí ẹ fẹ́ gbìn wọ́n sì jẹ́ mímọ́.
37 Se cair alguma coisa dos seus cadáveres sobre uma semente qualquer, esta ficará pura.
38 Ṣùgbọ́n bí ẹ bá ti da omi sí ohun ọ̀gbìn náà tí òkú wọn sì bọ́ sí orí rẹ̀ àìmọ́ ni èyí fún un yín.
38 Mas se se derramar água sobre a semente e alguma coisa dos seus cadáveres cair sobre ela, tê-la-eis por impura.
39 “ ‘Bí ẹran kan bá kú nínú àwọn tí ẹ lè jẹ, ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú rẹ̀ yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
39 Se morrer algum animal que vos é lícito comer, aquele que tocar o seu cadáver será impuro até a tarde.
40 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èyíkéyìí nínú òkú ẹranko náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú ẹranko yóò fọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wà ní àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
40 Quem comer de sua carne lavará suas vestes e será impuro até a tarde; e aquele que levar esse cadáver lavará suas vestes e ficará impuro até a tarde.
41 “ ‘Ìríra ni gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ jẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n.
41 Todo animal que se arrasta sobre a terra vos será uma coisa abominável: não se comerá dele.
42 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ń rìn ká orí ilẹ̀ yálà ó ń fàyàfà tàbí ó ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, tàbí ó ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsẹ̀ rìn ìríra ni èyí.
42 Não comereis animal algum que se arrasta sobre a terra, tanto aqueles que se arrastam sobre o ventre como aqueles que andam sobre quatro ou mais pés: tê-los-eis em abominação.
43 Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fi ohun kan tí ń rákò, sọ ara yín di ìríra, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fi wọ́n sọ ara yín di aláìmọ́, tí ẹ̀yin yóò fi ti ipa wọn di eléèérí.
43 Não vos torneis abomináveis, comendo um desses répteis, e não vos façais impuros por eles, porque vos tornaríeis imundos.
44 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ torí pé mo jẹ́ mímọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ ohunkóhun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀.
44 Pois eu sou o Senhor, vosso Deus. Vós vos santificareis e sereis santos, porque eu sou santo. Não vos contaminareis com esses animais que se arrastam sobre a terra,
45 Èmi ni Olúwa tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín torí náà, ẹ jẹ́ mímọ́ torí pé mímọ́ ni èmi.
45 porque eu sou o Senhor que vos tirou da terra do Egito para ser o vosso Deus. Sereis santos porque eu sou santo.
46 “ ‘Àwọn wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹranko, ẹyẹ, gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi àti àwọn ẹ̀dá tí ó ń rìn lórí ilẹ̀.
46 Tal é a lei relativa aos quadrúpedes, às aves, a todos os seres vivos que se movem na águas e a todos aqueles que se arrastam sobre a terra.
47 Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrín àìmọ́ àti mímọ́ láàrín ẹ̀dá alààyè, tí ẹ le jẹ àti èyí tí ẹ kò le jẹ.’ ”
47 Essa lei vos fará discernir o que é puro do que é impuro, o animal que pode ser comido do que não pode."
Atalhos do teclado
- Capítulo anterior←
- Próximo capítulo→
- Versículo anteriork
- Próximo versículoj
- Limpar seleçãoEsc
- Esta ajuda?
Estude este capítulo no WhatsApp
Peça à IA da Bíblia Fala para explicar Levítico 11, comparar traduções ou montar um estudo — tudo direto pelo WhatsApp.