Juízes 4

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YOR) vs NVI

Sair da comparação
NVI Nova Versão Internacional
1 Lẹ́yìn ikú Ehudu, àwọn ènìyàn Israẹli sì tún ṣẹ̀, wọ́n ṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa.
1 Depois da morte de Eúde, mais uma vez os israelitas fizeram o que o Senhor reprova.
2 Nítorí náà Olúwa jẹ́ kí Jabini, ọba àwọn Kenaani, ẹni tí ó jẹ ọba ní Hasori, ṣẹ́gun wọn. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Sisera ẹni tí ń gbé Haroseti-Hagoyimu.
2 Assim o Senhor os entregou nas mãos de Jabim, rei de Canaã, que reinava em Hazor. O comandante do seu exército era Sísera, que habitava em Harosete-Hagoim.
3 Nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) kẹ̀kẹ́ ogun irin, ó sì ń pọ́n Israẹli lójú gidigidi fún ogún ọdún, Israẹli ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́.
3 Os israelitas clamaram ao Senhor, porque Jabim, que tinha novecentos carros de ferro, os havia oprimido cruelmente durante vinte anos.
4 Debora, wòlíì obìnrin, aya Lapidoti ni olórí àti aṣíwájú àwọn ará Israẹli ní àsìkò náà.
4 Débora, uma profetisa, mulher de Lapidote, liderava Israel naquela época.
5 Òun a máa jókòó ṣe ìdájọ́ ní abẹ́ igi ọ̀pẹ tí a sọ orúkọ rẹ̀ ní ọ̀pẹ Debora láàrín Rama àti Beteli ní ilẹ̀ òkè Efraimu, àwọn ará Israẹli a sì máa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti yanjú èdè-àìyedè tí wọ́n bá ní sí ara wọn, tàbí láti gbọ́ ohùn Olúwa láti ẹnu rẹ̀.
5 Ela se sentava debaixo da tamareira de Débora, entre Ramá e Betel, nos montes de Efraim, e os israelitas a procuravam, para que ela decidisse as suas questões.
6 Ní ọjọ́ kan, ó ránṣẹ́ pe Baraki ọmọ Abinoamu, ẹni tí ń gbé ní Kedeṣi ní ilẹ̀ Naftali, ó sì wí fún un pé, “Olúwa, Ọlọ́run Israẹli pa á ní àṣẹ fún un pé, ‘Kí ó kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn akọni ọkùnrin jọ láti ẹ̀yà Naftali àti ẹ̀yà Sebuluni bí ẹgbẹ́ ogun, kí o sì síwájú wọn lọ sí òkè Tabori.
6 Débora mandou chamar Baraque, filho de Abinoão, de Quedes, em Naftali, e lhe disse: "O Senhor, o Deus de Israel, lhe ordena que reúna dez mil homens de Naftali e Zebulom e vá ao monte Tabor.
7 Èmi yóò sì fa Sisera olórí ogun Jabini, pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ àti àwọn ogun rẹ, sí odò Kiṣoni èmi yóò sì fi lé ọ lọ́wọ́ ìwọ yóò sì ṣẹ́gun wọn níbẹ̀.’ ”
7 Ele fará que Sísera, o comandante do exército de Jabim, vá atacá-lo, com seus carros de guerra e tropas, junto ao rio Quisom mulher, e os entregará em suas mãos".
8 Baraki sì dá a lóhùn pé, “Èmi yóò lọ tí ìwọ ó bá bá mi lọ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ.”
8 Baraque disse a ela: "Se você for comigo, irei; mas, se não for, não irei".
9 Debora dá a lóhùn pé, “ó dára, èmi yóò bá ọ lọ. Ṣùgbọ́n ọlá ìṣẹ́gun tí o ń lọ yìí kò ní jẹ́ tìrẹ, nítorí Olúwa yóò fi Sisera lé obìnrin lọ́wọ́,” báyìí Debora bá Baraki lọ sí Kedeṣi.
9 Respondeu Débora: "Está bem, irei com você. Mas saiba que, por causa do seu modo de agir, a honra não será sua; porque o Senhor entregará Sísera nas mãos de uma mulher". Então Débora foi a Quedes com Baraque,
10 Nígbà tí Baraki pe ẹ̀yà Sebuluni àti ẹ̀yà Naftali sí Kedeṣi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) akíkanjú ọkùnrin ogun tẹ̀lé e, Debora pẹ̀lú bá wọn lọ.
10 onde ele convocou Zebulom e Naftali. Dez mil homens o seguiram, e Débora também foi com ele.
11 Ǹjẹ́ Heberi ọmọ Keni, ti ya ara rẹ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Keni, àní àwọn ọmọ Hobabu, àna Mose, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ títí dé ibi igi óákù Saananimu, tí ó wà ni agbègbè Kedeṣi.
11 Ora, o queneu Héber se havia separado dos outros queneus, descendentes de Hobabe, sogro de Moisés, e armou a sua tenda junto ao carvalho de Zaanim, perto de Quedes.
12 Nígbà tí a sọ fún Sisera pé Baraki ọmọ Abinoamu ti kó ogun jọ sí òkè Tabori,
12 Quando disseram a Sísera que Baraque, filho de Abinoão, tinha subido o monte Tabor,
13 Sisera kó gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun irin rẹ̀ tí ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, láti Haroseti tí àwọn orílẹ̀-èdè wá sí odò Kiṣoni.
13 Sísera reuniu seus novecentos carros de ferro e todos os seus soldados, de Harosete-Hagoim ao rio Quisom.
14 Debora sì wí fún Baraki pé, “Lọ! Lónìí ni Olúwa fi Sisera lé ọ lọ́wọ́, Olúwa ti lọ síwájú rẹ.” Baraki sì síwájú, àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sì tẹ̀lé e lẹ́yìn, wọ́n sì kọjá sí òkè Tabori.
14 E Débora disse também a Baraque: "Vá! Este é o dia em que o Senhor entregou Sísera em suas mãos. O Senhor está indo à sua frente! " Então Baraque desceu o monte Tabor, seguido por dez mil homens.
15 Olúwa sì mú ìdàrúdàpọ̀ wá sí àárín ogun Sisera, Olúwa sì fi ojú idà ṣẹ́gun Sisera àti àwọn oníkẹ̀kẹ́ ogun àti ọmọ-ogun orí ilẹ̀ ní iwájú Baraki. Sisera sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ ó sì fi ẹsẹ̀ sálọ.
15 Diante do avanço de Baraque, o Senhor pela espada derrotou Sísera e todos os seus carros de guerra e o seu exército, e Sísera desceu do seu carro e fugiu a pé.
16 Baraki àti àwọn ogun rẹ̀ sì lé àwọn ọ̀tá náà, àwọn ọmọ-ogun orílẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn títí dé Haroseti ti àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo ogun Sisera sì ti ojú idà ṣubú, kò sí ọ̀kan tí ó lè sálà tàbí tí ó wà láààyè.
16 Baraque perseguiu os carros de guerra e o exército até Harosete-Hagoim. Todo o exército de Sísera caiu ao fio da espada; não sobrou um só homem.
17 Ṣùgbọ́n Sisera ti fi ẹsẹ̀ sálọ sí àgọ́ Jaeli aya Heberi ẹ̀yà Keni: nítorí ìbá dá ọ̀rẹ́ àlàáfíà wà láàrín Jabini ọba Hasori àti ìdílé Heberi ti ẹ̀yà Keni.
17 Sísera, porém, fugiu a pé para a tenda de Jael, mulher do queneu Héber, pois havia paz entre Jabim, rei de Hazor, e o clã do queneu Héber.
18 Jaeli sì jáde síta láti pàdé Sisera, ó sì wí fún un pé, “Wọlé sínú àgọ́ mi, Olúwa mi, wọlé wá má ṣe bẹ̀rù nítorí pé ààbò ń bẹ fún ọ.” Ó sì yà sínú àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ bò ó.
18 Jael saiu ao encontro de Sísera e o convidou: "Venha, entre na minha tenda, meu senhor. Não tenha medo! " Ele entrou, e ela o cobriu com um pano.
19 Sisera wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ́ mí, jọ̀wọ́ fún mi ní omi mu.” Ó sì ṣí awọ wàrà kan, ó sì fún un mu ó sì tún daṣọ bò ó padà.
19 "Estou com sede", disse ele. "Por favor, dê-me um pouco de água. " Ela abriu uma vasilha de leite feita de couro, deu-lhe de beber, e tornou a cobri-lo.
20 Sisera sọ fún Jaeli pé, “Kí ó dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, àti pé bí ẹnikẹ́ni bá béèrè bóyá òun wà níbẹ̀ kí ó sọ pé, ‘Kò sí ẹnìkankan ní ibẹ̀.’ ”
20 E Sísera disse à mulher: "Fique à entrada da tenda. Se alguém passar e perguntar se há alguém aqui, responda que não".
21 Ṣùgbọ́n Jaeli ìyàwó Heberi mú ìṣó àgọ́ tí ó mú àti òòlù ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì yọ́ wọ inú ibi tí ó sùn, nígbà tí ó ti sùn fọnfọn, nígbà náà ni ó kan ìṣó náà mọ́ òkè ìpéǹpéjú rẹ̀, ó sì wọlé ṣinṣin, ó sì kú.
21 Entretanto, Jael, mulher de Héber, apanhou uma estaca da tenda e um martelo e aproximou-se silenciosamente enquanto ele, exausto, dormia um sono profundo. E cravou-lhe a estaca na têmpora até penetrar o chão, e ele morreu.
22 Nígbà tí Baraki dé bí ó ti ń lépa Sisera, Jaeli láti pàdé rẹ̀, wá, èmi yóò fi ẹni tí ìwọ ń wá hàn ọ́, báyìí ni ó tẹ̀lé e wọ inú àgọ́ lọ, kíyèsi Sisera dùbúlẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú ìṣó àgọ́ ní agbárí rẹ̀ tí a ti kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin tí ó sì ti kú.
22 Baraque passou à procura de Sísera, e Jael saiu ao seu encontro. "Venha", disse ela, "eu lhe mostrarei o homem que você está procurando. " E entrando ele na tenda, viu ali caído Sísera, morto, com a estaca atravessada nas têmporas.
23 Ní ọjọ́ náà ni Ọlọ́run ṣẹ́gun Jabini ọba àwọn ará Kenaani ní iwájú àwọn ẹ̀yà Israẹli.
23 Naquele dia Deus subjugou Jabim, o rei cananeu, perante os israelitas.
24 Ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli sì le, ó sì ń lágbára síwájú àti síwájú sí i lára Jabini ọba Kenaani, títí wọ́n fi run òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.
24 E os israelitas atacaram cada vez mais a Jabim, o rei cananeu, até que eles o destruíram.

Ler em outra tradução

Comparar com outra

Estude este capítulo no WhatsApp

Peça à IA da Bíblia Fala para explicar Juízes 4, comparar traduções ou montar um estudo — tudo direto pelo WhatsApp.